Nitori pe wọn tapa si ofin Korona, ijọba ti ile-igbafẹ Queens Park, wọn tun gba iwe aṣẹ wọn

 Jide Alabi

Nnkan ko ṣenuure fun ile-igbafẹ kan ti wọn n pe ni Queens Park, to wa ni Oniru, nipinlẹ Eko. Eyi ko sẹyin bi ijọba ṣe ti pa, ti wọn si tun gba iwe aṣẹ wọn nitori bi wọn ko ṣe tẹlẹ ilana ofin Korona tijọba Eko la silẹ lasiko ti awọn kan lo ibẹ fun ayẹyẹ lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii.

Kọmiṣanna fun eto iṣẹ ọna, aṣa ati igbafẹ, Usamat Akinbile-Yusuff, sọ pe igbesẹ lati gba iwe aṣẹ ile-igbafẹ naa ti ijọba gbe yii pọn dandan, o si wa fun anfaani awọn araalu lapapọ.

O waa rọ awọn ile-igbafẹ yooku ki wọn fi ti awọn eeyan yii ṣe arikọgbọn nipa titẹle ofin ati ilana ti ijọba gbe kalẹ lori arun Korona. Kọmiṣanna ni ẹnikẹni to ba kọ lati tẹle awọn ilana yii yoo sọ anfaani lati ṣiṣẹ niluu Eko nu.

O ni ọna kan ṣoṣo ti opin fi le de ba arun yii nipinlẹ naa ni ti onikaluku ba ṣe ojuṣe rẹ, to si tẹle ofin ti ajọ eleto ilera la kalẹ.

 

Ọga agba fun ileeṣẹ to wa fun idaabo bo araalu nipinlẹ Eko (Lagos State Safety Commission), Lanre Mọjọla, sọ pe, o di dandan kawọn ti ile-igbafẹ naa nitori ayẹyẹ kan ti wọn ṣe nibẹ ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, ti wọn ko tẹle ofin ati ilana Korona ti ijọba la kalẹ.

O waa rọ awọn ile-igbafẹ gbogbo, awọn ibi apejẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ pe ki wọn so ewe agbejẹ mọwọ, ki wọn si tẹle ofin ti ijọba la kalẹ, bii bẹẹ kọ, awọn yoo gba iwe aṣẹ wọn.

O tun ṣekilọ fun awọn ti wọn maa n ja ilẹkun ti ijọba ba ti pa, ti wọn si maa n fa awọn iwe ikede pe wọn ti ti wọn ya pe ọwọ ofin lawọn yoo fi mu wọn.

O waa rọ awọn to ni ile-ọti, awọn to ni ibi apejẹ ati ile-igbafẹ gbogbo pe ki wọn ri i pe awọn n tẹle ofin ati ilana to yẹ lori arun Korona to wa nita, o ni nipa bẹẹ ni arun naa ko fi ni i maa tan kiri niluu Eko.

Leave a Reply