Monisọla Saka
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti paṣẹ fun ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ nipinlẹ naa lati bẹrẹ iwadii ni kiakia lori ọrọ akẹkọọ ọmọ ọdun mẹwaa kan, Barinada Marvelous, ti ọga ileewe Ọdọmọla Junior Secondary School, Ẹpẹ, nipinlẹ Eko, le kuro nileewe nitori pe o fi iwe ipolongo to ni aworan Peter Obi yi iwe rẹ lẹyin. Niṣe ni ọga ileewe naa le akẹkọọ yii lọ sile pẹlu lẹta, o ni o fi beba ti wọn fi ṣe ipolongo ibo fun Peter Obi, lasiko ibo aarẹ to waye loṣu to kọja yii, we iwe rẹ lẹyin, ati pe ipinlẹ APC ni Eko, ki i ṣe ti Peter Obi.
Ninu aworan kan ti baba ọmọ naa gbe sori ayelujara lati fi aidunnu rẹ han lori bi wọn ṣe le ọmọ rẹ kuro nileewe nitori pe o fi posita Peter Obi ti ẹgbẹ Labour ranbu iwe rẹ, lo ti ṣafihan iwe pelebe tẹẹrẹ kan ti ọga ileewe naa kọ ọrọ si, nibi to ti paṣẹ pe pe ki ọmọ naa lọọ sinmi nile si pe:
“Iwọ Omidan Marvelous, ti kilaasi ipele girama kekere keji (JSS2), ni a ti yọnda rẹ bayii lati maa lọ sile, ko o lọọ maa polongo ibo fun Peter Obi, pẹlu bi awọn olugbe ipinlẹ Eko ko ṣe lọwọ si i, ti wọn si ta ko eyi”.
Apa kan ọrọ ti babab ọmọ naa kọ si abẹ iwe pelebe ti wọn fi le ọmọ ẹ nileewe ni, “Eyi ni lati fi to yin leti pe wọn ti le ọmọ mi obinrin, Marvelous Barinada, kuro nileewe Ọdọmọla Secondary School, lonii, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2023. Ọga ileewe funra rẹ lo kọ iwe gbele-ẹ fun un, nitori pe wọn ni ọmọ mi fi beba ipolongo ibo Peter Obi yi ara iwe rẹ ko ma baa tete ya, ọmọ ọdun mẹwaa pere si ni ọmọ ta a n wi yii o.
Ọmọ ti ko mọ nnkan kan nipa oṣelu, ṣugbọn ti wọn le e kuro nileewe lai sọ fawọn obi ẹ, nitori wọn ni Peter Obi ati ẹgbẹ Labour Party la n ṣatilẹyin fun.
‘‘Ẹ jọọ, ṣe ohun ti ọga agba ileewe yii ṣe daa, ẹyin naa ẹ wo nnkan to kọ sori lẹta ọhun, to ba si ya nisinyii, a maa maa sọ pe ọmọ Naijiria kan naa ni gbogbo wa.
Ija awọn alatilẹyin Obi ree o, lati le gba ominira yin.
Ẹyin tẹ ẹ n ṣe ti Obi, ẹ ji giri, kẹ ẹ gba ipinlẹ Eko yin pada”.
Kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ Eko, Arabinrin Fọlaṣade Adefisayọ, ti kede l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, pe gomina ti buwọ lu igbesẹ lori bi awọn yoo ṣe ranṣẹ pe ọga agba ileewe naa lati waa sọ tẹnu ẹ ati gbogbo ohun to mọ nipa iṣẹlẹ naa.
O ni, “Ijọba ipinlẹ Eko, ileeṣẹ eto ẹkọ nipinlẹ naa atawọn ileeṣẹ yooku ko le paṣẹ fun ọga agba ileewe girama, olukọ tabi oṣiṣẹ ileewe kankan lati hu iru iwa bẹẹ yẹn”.
Kọmiṣanna yii waa fawọn araalu lọkan balẹ pe awọn yoo yanju ọrọ naa ni ibamu pẹlu ofin ileeṣẹ awọn, nitori awọn o gba, bẹẹ lawọn o le fọwọ si lile akẹkọọ lọ sile.
Bakan naa ni Adefisayọ tun mẹnuba ọga agba ileewe mi-in lagbegbe Odogunyan, Ikorodu, nipinlẹ Eko, ti wọn mu ninu kamẹra aṣofofo lasiko ti wọn gbe e sori ayelujara, pẹlu bo ṣe n fọgbọn polongo oludije sipo gomina to wu u lati ọkan rẹ niwaju awọn akẹkọọ, eyi ti wọn ni o ti n kawọ pọnyin rojọ lọwọ niwaju awọn alaṣẹ fun ijiya to tọ.
Adefisayọ fi kun un pe awọn yoo ṣewadii to munadoko lori ọrọ yii, ẹnikẹni ti aje iwa ibajẹ naa ba si ṣi mọ lori yoo fimu kata ofin gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ofin awọn oṣiṣẹ ijọba.