Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ṣe ni idunnu ṣubu layọ fawọn eeyan ilu Ikarẹ-Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun, pẹlu bi ijọba ipinlẹ Ondo ṣe kede mimu adinku ba ofin konile-gbele to ti wa niluu ọhun lati bii ọsẹ kan sẹyin.
Ikede tuntun naa waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanla, oṣu yii. Ni ibamu pẹlu atẹjade ti Kọmiṣanna feto iroyin, Abilekọ Bamidele Ademọla-Ọlatẹju, fi ṣọwọ sawọn oniroyin.
Ọlatẹju ni ijọba ipinlẹ Ondo, labẹ iṣakoso Arakunrin Rotimi Akeredolu, ti gba ẹbẹ awọn eeyan ilu Ikarẹ yẹwo nipa yiyi ofin konile-gbele oni wakati mẹrinlelogun to ti wa nilẹ lati bii ọsẹ kan sẹyin pada si wakati mejila pere, iyẹn aago mẹfa alẹ si mẹfa aarọ.
Ọlatẹju ni inu gomina ko dun rara si rogbodiyan to n fi gbogbo igba waye niluu Ikarẹ, ati pe ijọba ti ṣetan lati fofin de Olukarẹ tilu Ikarẹ-Akoko, Ọba Akadiri Momoh, ati ojugba rẹ to jẹ Ọwa-Ale Iyọmẹta, Ọba Adeleke Adegbitẹ, ki wọn si le awọn mejeeji kuro lori itẹ ti wahala mi-in ba ṣeesi tun sọ niluu naa nitori ohunkohun.
O ni ijọba ti ṣe agbekalẹ igbimọ ẹlẹni marun-un kan, ninu eyi ta a ti ri, Baṣọrun Sẹhinde Arogbọfa (akọwe ẹgbẹ Afẹnifẹre tẹlẹ ri) gẹgẹ bii alaga, Ọgbẹni Joseph Dele Adesanmi ni Akọwe igbimọ naa, nigba ti Oloye Jimoh Afọlabi Ẹkungba, Dokita Tunji Abayọmi ati Abilekọ Ọrẹoluwa Agbayẹwa jẹ ọmọ ẹgbẹ.
Igbimọ ọhun lo ni wọn gbe kalẹ lati wa ọna abayọ si ohun to saaba maa n ṣokunfa rogbodiyan lagbagbe Ọkọja ati Ọlọkọ.
Bakan naa lo ni ijọba ti n gbe igbesẹ lati ṣawari itan Ọkọja, eyi to n fa wahala laarin awọn ọba alade mejeeji, ki wọn le mọ ọna ati ba wọn pari aawọ naa nitubi inubi.
Abilekọ Ọlatẹju ni ijọba ti gbẹsẹ le ọrọ oye Ọlọkọja ti Ọkọja lati asiko yii lọ, bẹẹ ni ko si ẹnikẹni to gbọdọ maa pe ara rẹ ni Oloye agbegbe ọhun mọ, yala lati ọdọ Olukarẹ tabi Ọwa-Ale.
Gbogbo awọn oloye keekeekee to wa ni Ọkọta lo ni ijọba tun ti gbẹsẹ le, o ni ẹnikẹni to ba jade lati pe ara rẹ ni oloye kan lagbegbe naa yoo ri pípọ́n oju ijọba.
Lati bii ọsẹ kan sẹyin tijọba ti kede ofin konile gbele oni wakati mẹrinlelogun gbako latari rogbodiyan nla to bẹ silẹ lasiko ti wọn n ṣe ayẹyẹ orikadun kanifa lagbegbe Ọkọja, ninu eyi tawọn eeyan kan ti ku, ti wọn si tun ba ọpọlọpọ dukia jẹ ni nnkan ko ti fara rọ mọ niluu Ikarẹ Akoko.
Gbogbo ọja, awọn ṣọọbu, banki atawọn ileesẹ to wa nigboro ilu naa ni wọn ti pa patapata, ti ko si sẹni to lori laya lati jade lọ sibikibi latari aṣẹ tijọba fun awọn ẹsọ alaabo lati fi pampẹ ofin gbe ẹnikẹni to ba tẹ ofin naa loju.
Ko si ọkọ tabi ọlọkada to gbọdọ ṣiṣẹ laarin ilu, gbogbo awọn awakọ ati arinrin-ajo to yẹ ki wọn gba Ikarẹ kọja ko ṣe bẹẹ mọ, ọna Akungba si Ọka Akoko, lo ku ti wọn n rin.
Ere lawọn eeyan ilu Ikarẹ kọkọ pe ọrọ ọhun, gbogbo ero wọn si ni pe dandan ni ki ìjọba Akeredolu yi ofin naa pada nigba tawọn akẹkọọ ba wọle fun saa eto ẹkọ́ keji lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nitori inu gomina ko ni i dun ki awọn ileewe yooku wọle ki wọn si tilẹkun pa mọ awọn akẹkọọ ti Ikarẹ sinu ile.
Lẹyin ti ilẹ ọjọ Aje, Mọnde, mọ, ṣugbọn ti gomina ko yi ipinnu rẹ pada, ti gbogbo ile-iwe, ọja atawọn ṣọọbu ṣi wa ni titi pa lawọn araalu too mọ kinni ọhun lọran nla.
Lati igba naa si lawọn eeyan ti n bẹbẹ, ti wọn si n parọwa si Aketi ko fọwọ wọnu, bi ko tilẹ fẹẹ ro ohunkohun, wọn ni o yẹ ko ro ti awọn ọmọ ile-iwe ti wọn ko ni i le ba awọn ẹgbẹ wọn pe nipinlẹ Ondo, ati tawọn eeyan mi-in ti ebi ti fẹẹ pa ku sile latari airi iṣe ṣe, eyi ti yoo fun wọn lanfaani ati rowo jẹun.
Lara awọn to rawọ ẹbẹ si gomina ni Olubaka ti Ọka Akoko, Ọba Yusuf Adebori Adelẹyẹ, atawọn mi-in.