Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn ọdọ tun gbe iwọde wọn gba ọna ara lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, pẹlu bi wọn ṣe rọ da si gbangba títì Iwo Road lalẹ pẹlu abẹla lọwọ kaluku wọn, wọn lawọn n ṣe iṣọ oru ni iranti awọn ẹgbẹ awọn ti awọn ọlọpaa yinbọn pa niluu Ogbomọṣọ ni. Oriṣiiriṣii orin aro ni wọn kọ pẹlu abẹla lọwọ. A gbọ pe niṣe ni wọn si ṣe iwọde ọhun di nnkan bii aago marun-un idaji ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.