Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti rawọ ẹbẹ si Aarẹ Muhammadu Buhari lati sinmi lilepa Oloye Sunday Adeyẹmọ, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, kaakiri.
Ninu lẹta kan ti Akọwe iroyin Oluwoo, Alli Ibraheem, kọ ranṣẹ si Buhari lorukọ Kabiesi ni Oluwoo ti sọ pe ọmọde ki i mọ ẹkọ ọ jẹ ko ma ra a lọwọ ni ọrọ wahala ti Igboho ko ara rẹ si yii.
O ni ọpọlọpọ ori-ade lo gba a nimọran nigba to bẹrẹ ijijagbara rẹ pe dandan ni ki Orileede Oodua da duro, ṣugbọn to kọ eti ikun si imọran awọn agba.
Oluwoo ṣalaye pe pẹlu bi gbogbo nnkan ṣe waa da bayii, Sunday Igboho ti kẹkọọ pe Naijiria ko ṣee pin si wẹwẹ lasiko ti a wa yii, ati pe ko sẹni to le doju ija kọ ijọba.
Kabiesi sọ siwaju pe “Gẹgẹ bii Musulumi, gbogbo wa la mọ pe ọjọ idariji ni ọjọ Jimọh jẹ, idi niyi ti mo fi n bẹ Aarẹ Muhammadu Buhari lati fori jin Sunday Adeyẹmọ.
“A kilọ fun un to. Ẹni to ba mọ itan wahala to mu ẹmi awọn eeyan bii Moshood Kaṣimawo Ọlawale Abiọla ati Kensaro Wiwa lọ yoo mọ pe ninu iṣọkan ni agbara wa wa.
“Sunday Adeyemo di gbajugbaja nipasẹ jija fun awọn ti wọn ba fọwọ ọla gba loju lawujọ, mo si maa n ba a sọrọ nigbakuugba ti mo ba gbọ ohunkohun nipa rẹ. O wa si aafin mi lọdun 2018, mo si gba a nimọran, ṣugbọn ko mọ iyatọ laarin didoju ija kọ ijọba ati jija fun ẹya ẹni.
“O to asiko kan to bẹrẹ si i bu gbogbo eeyan, mo wa lara awọn to kọkọ fẹsun kan nitori ipolongo ki orileede yii wa lọkan ti mo n ṣe. Gẹgẹ bii baba, mo ti dariji i, mo wa n bẹ Aarẹ Buhari pe ko foriji ọmọ wa ologo yii.
“Ope ni ninu nnkan to jẹ mọ tijọba. Ẹbun pataki lo jẹ fun iran Yoruba. O ti ṣeleri lati feti si imọran wa. Mo bẹ Aarẹ lati paṣẹ fun awọn agbofinro lati tuukanna lẹyin ọrun rẹ. Mo gbagbọ pe ṣiṣe bẹẹ yoo tun mu ki iṣọkan Naijiria tẹsiwaju. Mo ṣeleri lati mu Igboho wa fun ipade alaafia nitori oju rẹ ti ri to, yoo si maa kiyesi ihuwasi rẹ latoni lọ.”
Oluwoo wa gboṣuba fun Buhari lori ọna to n gba lati gbogun ti iwa igbesunmọmi ati awọn iwa janduku lorileede yii pẹlu bo ṣe n mu idagbasoke ba gbogbo ẹkajẹka.