Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọru, Wẹsidee, ọṣẹ yii, lawọn akekọọ Musulumi nileewe Baptist, niluu Ijagbo, nipinlẹ Kwara, ṣewọde lọ si ile-ijọba to wa niluu Ilọrin, latari pe awọn alaṣẹ ileewe naa yari pe wọn o gbọdọ lo ijaabu mọ ninu ọgba ileewe ọhun.
Tẹ o ba gbagbe, loṣu to kọja ni awuyewuye waye lawọn ileewe ijọba to jẹ ti awọn ijọ ti Baptist da silẹ, nibi ti wọn ti sọ pe awọn Musulumi lawọn ileewe naa ko gbọdọ lo ijaabu wọ awọn inu ọgba ileewe naa mọ, ijọba si paṣẹ pe ki awọn alasẹ lawọn ileewe ọhun gba ọmọ to wu laaye lati maa lo ijaabu, sugbọn ti awọn alaṣẹ ileewe naa ko tẹle aṣẹ yii, eyi lo mu ki awọn ọmọ Musulumi lawọn ileewe Baptist niluu Ijagbo ṣe iwọde lọ si ile-ijọba, ti wọn si rọ ijọba, labẹ iṣejọba Gomina Abdulrazaq, lati da si ọrọ naa tori pe wọn n fi ẹtọ awọn ọmọ Musulumi du wọn.