Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Oku ọkunrin ẹni ọdun mejidinlaaadọta kan, Sali Nasiru, ti awọn ajinigbe ji gbe ninu sọọmeeli kan ni Aisẹgba-Ekiti, ni wọn ti ri ninu igbo kan lagbegbe naa.
Nasiru, to n ṣe iṣẹ lagilagi ni sọọmeeli ọhun lawọn ajinigbe ji gbe lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, lasiko to n ṣiṣẹ ninu Sọọmeli naa.
Awọn ọdẹ ibilẹ ati ẹṣọ Amọtẹkun ni wọn sadeede ba oku rẹ ninu agbara ẹjẹ ninu igbo kan to wa loju ọna to lọ lati ilu Aisẹgba si Ikarẹ-Akoko, nipinlẹ Ondo.
Oloye kan niluu naa to ba akọroyin wa sọrọ sọ pe ko ju bii ibusọ mẹfa si itosi ibi ti wọn ti ji i gbe ni wọn ti ri oku rẹ.
Ọkunrin yii ni awọn ajinigbe ti wọn gun ọkada ni wọn sadeede ya wọ ileeṣẹ lagilagi to wa ni Aisẹgba-Ekiti yii, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn soke, lẹyin naa ni wọn ji ọkunrin yii gbe nibi to ti n ṣiṣẹ lọwọ.
Oloye ti ko fẹ ka darukọ oun naa ni ẹni to ni ileeṣẹ ti wọn ti n lagi yii ni wọn fẹẹ waa ji gbe, ṣugbọn bi iyẹn ṣe ri wọn lọọọkan lo fi ọkọ ayọkẹlẹ rẹ silẹ, to kan lugbẹ.
Bi wọn ṣe debẹ ni wọn ra Nasiru mu, ti wọn si gbe e lọ. Lẹyin wakati diẹ ti wọn ji ọkunrin yii gbe ni awọn ọdẹ ibilẹ, fijilante ati Amọtẹkun kora wọn jọ, ti wọn si bẹrẹ igbesẹ lati ri ẹni ti wọn ji gbe naa gba silẹ. Ṣugbọn niṣe ni wọn ṣadeede ba oku rẹ ninu igbo kan ti ko ju bii kilomita mẹfa si ibi ti wọn ti ji i gbe lọjọ kẹta.
Ọkan lara awọn ọdẹ ibilẹ to wa lara awọn to ri oku ọmọkunrin yii, Akin Okilo, ṣalaye fun ALAROYE pe
awọn ajinigbe naa ti kọkọ pe awọn mọlẹbi ọkunrin naa nirọlẹ ọjọ ti wọn ji i gbe, ti wọn si beere ọgọrun-un miliọnu.
Wọn ni ọmọkunrin yii ba awọn mọlẹbi rẹ sọrọ pe oun wa lakata awọn ajinigbe naa, ṣugbọn ko raaye sọ apa ibi ti oun wa.
A gbọ pe wọn ti gbe oku Nasiru lọ si ile igbokuu pamọ si ni agbegbe naa, awọn mọlẹbi rẹ si ti bẹrẹ igbesẹ lati sin oku naa ni kete tawọn agbofinro ba ti pari iwadii lori ọrọ naa.
Ọga awọn ọmọ ogun Amọtẹkun nipinlẹ Ekiti, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ, sọ pe ibanujẹ lo jẹ pẹlu bi awọn ṣe ri oku ọkunrin naa ninu igbo. O ni awọn Amọtẹkun ti wa ninu igbo, ti wọn si n gbiyanju bi wọn yoo ṣe ri i ko too di pe oku rẹ ni wọn ri.