Adewumi Adegoke
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni iwadii ṣi n lọ lori ọrọ baale ile kan, Taofeek Gbọlagade, to lu iyawo rẹ to wa ninu oyun lalubami nitori to ni iyẹn ko tọju ounjẹ saari fun oun.
Gẹgẹ bi iweeroyin Vanguard ṣe sọ, ni nnkan bii aago mẹrin oru ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ni ede aiyede bẹ silẹ laarin obinrin yii ati ọkọ rẹ lori ọrọ ounjẹ saari nile wọn to wa ni Ogbere Housing Estate, niluu Ibadan.
Awọn tọrọ naa ṣoju wọn sọ pe gbogbo igba ni ọkunrin yii maa n lu iyawo rẹ lori ọrọ ti ko to nnkan. Iru rẹ lo si ṣẹlẹ lọjọ Iṣẹgun yii nipa ounjẹ ti ọkunrin naa fẹẹ fi gbaawẹ. Wọn ni ko tiẹ ronu pe obinrin yii wa ninu oyun ọmọ keji to fẹẹ bi fun un to fi ki i mọlẹ, to si n na an bii igba ti eeyan ba n lu aṣọ ofi.
Wọn ni ẹkun ni obinrin naa sun lọ si ile awọn obi rẹ. Bẹẹ ni ọkọ rẹ paapaa sa lọ nigba to gbọ pe awọn agbofinro n wa oun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Adewale Osifẹsọ, fidii iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni iwadii ti n lọ lori iṣẹlẹ ọhun.