Jide Alabi
Nítorí tawọn ọlọpaa ko jẹ ki ọkunrin akọroyin to nileeṣẹ iroyin Sahara Reporter, Ọmọyẹle Ṣowore, lanfaani sí ìwé tawọn mọlẹbi ẹ ko wa fun un, ọkunrin naa ti ni ebi loun yóò máa fi pa ara oun bayii.
ALAROYE gbọ pe bi awọn eeyan ẹ ṣe ko awọn ìwé ẹ wa, ṣugbọn ti awọn ọlọpaa kọ láti ko o fun un lo fa a ti Ṣowore fi yari pé oun ko ni i jẹ ounjẹ ti wọn ba gbe fún òun, nitori oun ko le máa jẹun sikun, ki oun ma fún ọpọlọ oun lounjẹ.
Aja-fẹtọọ-ọmọniyan yii sọ pe bi oun ba ṣe n jẹun, bẹẹ gẹgẹ loun máa n fún ọpọlọ oun lounjẹ, ati pe awọn iwe ti oun máa n ka ni ounjẹ ti ọpọlọ oun máa n jẹ.
Ni bayii, ọkunrin oniroyin, to tun jẹ oloṣelu yii, ti sọ pe oun yóò bẹrẹ ifẹhonu han, oun yóò sì bẹrẹ sí i febi nla pa ara oun.
Bi Ṣowore ṣe bẹrẹ ifẹhonu hàn yii lawọn ti wọn jọ mu naa ti darapọ mọ ọn, ti gbogbo wọn sì ti lawọn ko ni i jẹun rara.
Laipẹ yii lawọn ẹṣọ agbofinro ko Ṣoworẹ atawọn eeyan ẹ nibi ti wọn ti n ṣewode lati wọnu ọdun tuntun.
Ṣaaju àsìkò yìí, ìyẹn lọjọ kẹta, oṣu kẹjọ, ọdún, 2019, làwọn ẹṣọ agbofinro DSS mu Ṣoworẹ, ti wọn si fi í sí atimọle wọn fún ọjọ mẹrinlelogoje (144).
Ẹsun tí wọn fi kan an ni pe oun naa n kowo pamọ́ lọna eru, ati pe o n gbero lati gbajọba mọ Ààrẹ Muhammadu Buhari, lọwọ.
Pẹlu ẹsun yii, ALAROYE gbọ pe awọn ẹṣọ agbofinro ko ri ẹri kan ko kalẹ lati fi ba a fa a.
Ninu wahala ọhun náà ni wọn ti gbe e lọ sile-ẹjọ, ṣugbọn ti wọn pada fún un ni beeli logunjọ, oṣu kọkanla, ọdun 2020, ti wọn sì pa a laṣẹ pé kò gbọdọ kúrò nílùú Abuja.