Nitori ti wọn ko gbowo atijọ lọsibitu, ọkunrin kan padanu iyawo ẹ toyun-toyun

Monisọla Saka

Niṣe ni baale ile kan, Malam Bello Fancy, bu gbaragada sẹkun lẹyin tiyawo ẹ, Shema’u Sani Labaran  ku toyuntoyun nitori wọn ko gbowo atijọ lọwọ rẹ lọsibitu ti wọn ti fẹẹ tọju rẹ, bẹẹ lọkunrin naa ko si ri owo tuntun ko silẹ.

Ọsibitu kan ti wọn n pe ni Abdullahi Wase Specialist Hospital, to wa niluu Kano, ni Bello gbe iyawo rẹ lọ fun itọju lasiko to n rọbi lọwọ. Baale ile yii ni ofin ti banki apapọ ilẹ wa ṣe lori gbedeke nina owo atijọ tawọn ileewosan naa si duro le lori, ti wọn fi taku pe awọn ko gba owo yii lọwọ oun lo ran iyawo oun lọrun ọsan gangan.

Fancy ni nitori pipẹ ti owo toun fi ṣọwọ sinu akanti ọsibitu naa tun pẹ ko too wọle lẹyin tawọn dokita kọ lati gba owo atijọ, lo ṣokunfa bi iyawo oun ṣe ku toyun-toyun. Baale ile yii ni o le ni wakati mẹta gbako tawọn dokita ko fi ya si obinrin yii rara.

Nigba to n ṣalaye fun ileeṣẹ Freedom Radio, o ni nigba to ti di pe asiko ti to loun gbe iyawo oun lọ sileewosan, ṣugbọn wọn lawọn ko fẹ owo atijọ. O ni nigba toun beere pe ki wọn gbe POS  jade, wọn lawọn ko ni, wọn ni koun fowo naa ṣọwọ sinu apo banki ọsibitu naa. Bello ni nigba toun sanwo si apo banki wọn tan, ti wọn si ti ja owo naa ninu asunwọn banki toun, awọn dokita yii ko tori bẹẹ wo apa ibi ti iyawo oun wa, o ni niṣe ni wọn taku pe afi ki awọn gbọ gbọngaun pe owo wọle sibẹ. Ṣugbọn ohun to ba ni lọkan jẹ ni pe o to bii wakati mẹta lẹyin ẹ ki wọn too ri owo toun fi ranṣẹ, nigba ti wọn yoo fi rowo ọhun, ẹpa o boro mọ.

Fancy ni, “Funra iyawo mi lo fẹsẹ ara rẹ rin wa sileewosan ọhun lati ile wa, ṣugbọn ko too di pe owo wọle sinu banki wọn, inira yẹn ti pọ ju fun un, ẹjẹ si ti bẹrẹ si i ya lara ẹ. Sibẹ naa, wọn o tori eyi ṣugbaa ẹ, titi di bii wakati mẹta lẹyin ẹ, iyẹn lẹyin ti wọn lawọn rowo ti mo fi ṣọwọ.

Lẹyin igba ti wọn bẹrẹ itọju rẹ yii ni wọn ri i pe ko ni i le da ọmọ yẹn bi funra ẹ, wọn ni afi kawọn ṣiṣẹ abẹ fun un. Lẹsẹkẹsẹ nibẹ naa ni mo ti sọ fun wọn pe mo fara mọ ọn, apo banki wọn naa ni wọn tun ni ki n fowo iṣẹ abẹ yẹn ranṣẹ si. Iyẹn naa tun to bii wakati mẹta ki wọn too ri i, nigba naa ni wọn bẹrẹ iṣẹ abẹ ti wọn fẹẹ ṣe fun iyawo mi. Amọ si iyalẹnu mi, oku ọmọ ni wọn gbe jade, iya ọmọ funra ẹ naa si tun ti doku”.

Ṣugbọn ninu alaye Dokita agba nileewosan ọhun, Dokita Rahila Garba, o ni irọ to jinna si ootọ ni gbogbo nnkan ti Ọgbẹni Fancy sọ, ati pe bẹẹ kọ ni ọrọ ri.

Bo si tilẹ jẹ pe awọn alaisan mi-in ti wọn wa l’ọsibitu ọhun lasiko iṣẹlẹ naa fidi rẹ mulẹ pe bi ọrọ ṣe ri ni ọkọ iyawo sọ ọ, wọn ni ohun toju awọn naa ri lasiko tawọn fẹẹ sanwo nibẹ ko ṣee fẹnu sọ, pẹlu bi wọn ṣe taku pe afi kawọn ṣe tiransifaa, ti wọn ko si tete ri owo tawọn san.

Agbẹnusọ ajọ ileewosan ijọba nipinlẹ naa, Malam Ibrahim Abdullahi, ni awọn ko ti i le fidi okodoro iṣẹlẹ naa mulẹ, nitori o ṣẹṣẹ de etiigbọ awọn ni.

Leave a Reply