Nitori ti won ko lo ibomu, awọn alaṣẹ ileewe le akẹkọọ meji danu nipinlẹ Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Nitori ti wọn ko lo ibomu lati daabo bo ara wọn kuro lọwọ kokoro arun Korona, ileewe ti wọn ti n kọ nipa eto ilera ati imọ ijinlẹ ni ipinlẹ Ọyọ, Oyo State College of Health Science and Technology (OYSCHST) ti da meji ninu awọn akẹkọọ wọn duro fun igba diẹ na.

Ọga agba ile ẹkọ naa, Ọgbẹni Ṣiji Ganiyu, funra rẹ lo fẹnu àṣẹ juwe ile fawọn akẹkọọ mejeeji ti wọn forukọ bo laṣiiri wọnyi l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Bakan naa lo ṣeleri pe gbogbo akẹkọọ to ba kùnà lati tẹle ilana gbogbo to wa fún idaabo bo ara ẹni lọwọ kiko kòkòrò àrùn Korona loun yóò máa lé kúrò ninu ọgbà ileewe naa lẹ́yẹ-ò-sọkà.

Ninu atẹjade ti Alukoro fún OYSCHST, Ọgbẹni Ṣọla Samuel Ọjẹwọle, fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan, o ni ìyá tí wọn fi jẹ awọn akẹkọọ yii waye nitori pe àwọn alákòóso ileewe naa ko fọwọ yẹpẹrẹ mu eto ilera, pàápàá ilana idaabobo-ara-ẹni kuro lọwọ kokoro arun Korona.

O waa rọ gbogbo ara ipinlẹ Ọyọ lati fọwọsowọpọ pẹlu Gomina Ṣeyi Makinde ninu ilakaka ijọba rẹ fopin sí itankalẹ kòkòrò àrùn aṣekupani naa

Leave a Reply