Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin ẹni ọdun mejilelogoji kan tawọn eeyan mọ si Awẹlẹwa lo gbiyanju lati pa ara rẹ niluu Akurẹ pẹlu bo ṣe lọọ binu ko si kanga nitori ti iyawo rẹ kọ lati fun un lowo to beere fun.
ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ yii waye laduugbo Ijọka, nibi ti ọkunrin naa n gbe, ni nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ keji, oṣu Kejila yii.
Wọn ni Awẹlẹwa ti kọkọ gbiyanju lati pa iyawo rẹ lasiko ti obinrin naa sun sinu yara, ọbẹ ni wọn lo yọ si i, to si fẹẹ du obinrin naa lọrun bii ẹran lati oju oorun, awọn ọmọ rẹ atawọn aladuugbo kan lo gba a silẹ lọwọ rẹ.
Ẹsun to fi kan iya ọlọmọ mẹrin ọhun to fi fẹẹ gba ẹmi rẹ ni pe obinrin naa ko jẹ oloootọ si oun mọ latari owo ti ko si lọwọ oun, bakan naa lo tun fẹsun kan an pe o kọ lati fun oun lowo ti oun beere lọwọ rẹ.
Bi awọn eeyan ṣe gba obinrin naa silẹ tan ti wọn si sare gbe e lọ si ọsibitu lati doola ẹmi rẹ ni Awẹlẹwa ọkọ rẹ ti sa jade, ti ko si pada wale lati igba naa títì di ọjọ Ẹti, Furaide, to kọja lọ yii, nigba tọrọ ọhun tun ba ọna mi-in yọ.
Iyawo Awẹlẹwa la gbọ pe o kọ jalẹ lati fun ọkọ rẹ lowo pẹlu bo ṣe kuna lati da ẹgbẹrun lọna igba Naira to kọ́kọ́ ya a pada.
Awọn ọrẹ rẹ kan ti wọn ri i níbi to ti n rin kiri ilu bii ọmọ ewurẹ ti iya rẹ sọnu ni wọn gba a nimọran pe ko ran ẹlẹbẹ si iyawo atawọn ana rẹ ti wọn fẹẹ fi ọlọpaa mu un ki ọkan rẹ le balẹ lati pada sile.
Loootọ lo gba si wọn lẹnu pẹlu bo ṣe duro nibi kan ti ko fi bẹẹ jinna si adugbo wọn, oun atawọn ti wọn jọ fẹẹ bẹ awọn ana rẹ si n reti ki wọn de ki awọn le ba wọn yanju ede-aiyede naa.
Bi Awẹlẹwa ṣe kofiri iyawo atawọn ẹbi rẹ, jinnijinni mu un nibi to duro si, ohun to wa lọkan rẹ ni pe ṣe ni wọn fẹẹ waa fi ọlọpaa mu oun. Ohun tawọn eeyan ṣakiyesi ni bo se bẹrẹ si i fẹyin rin, aga ti yoo fi jokoo ni wọn kọkọ ṣebi o n wa, kayeefi nla lo jẹ fun wọn nigba ti wọn deedee ri i to gori kanga kan to wa nitosi lọ, to si bẹ sinu rẹ jua.
Awọn eeyan to wa layiika ibi iṣẹlẹ ọhun la gbọ pe wọn sare sugbaa rẹ, wọn gbiyanju ati fa a yọ kuro ninu kànga naa ko too mu omi yo, wọn si gbe e lọ si ọsibitu kan, nibi to ti n gba itọju lọwọ.
A gbọ pe awọn ana ọkunrin yii si ni i lọkan lati fi ọlọpaa mu un lẹyin ti ara rẹ ba ya tan, nitori wọn ti lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa to wa ni teṣan Ala leti.