Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni ọkan lara awọn osisẹ ajọ ẹṣọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka tipinlẹ Kwara, Ọgbẹni A. Yusuf, wọ wahala lẹyin to doola awọn mẹta kan ti awọn ajinigbe ji gbe niluu Ilọrin, wọn da a duro lẹnu iṣẹ.
ALAROYE gbọ pe Yusuf lo ko awọn ọmọ ajọ naa sodi lati doola eeyan mẹta kan ti awọn ajinigbe ji gbe, to fi mọ Arabinrin Abdullateef ti wọn jigbe ninu kẹkẹ Napep lasiko to n lọ si agbegbe Lare-Gada, niluu Ilọrin, lati Ọja-Ọba, ni ọjọ kẹsan-an, osu Kọkanla, ọdun yii.
Yusuf wọ wahala lẹyin ti fọnran fidio kan gba ori ayelujara pe o ṣiṣẹ naa lọna aitọ, wọn ni ko gbaṣẹ lọwọ awọn ọga rẹ to fi lọ nipinlẹ naa.
Oṣiṣẹ ajọ ọhun ni Kwara, ta a forukọ bo laṣiri, sọ fun oniroyin wa pe arabinrin ti kẹkẹ Napep n ji gbe lọ lo fariwo ta, to si n pe awọn eniyan pe onikẹkẹ ti n gbe oun gba ibomiran lọ, bo tilẹ jẹ pe ọkunrin to gbe e parọ pe tori sunkẹrẹ-fakẹrẹ ni oun ṣe n gba ibomiiran lọ, to si wa obinrin naa lọ sinu igbo, nibi ti wọn ko awọn eniyan pamọ si lati maa fi iya jẹ wọn, ko too di pe Yusuf ko awọn eeyan rẹ sodi, ti wọn si doola obinrin naa ati awọn meji miiran ni ibuba awọn ajinigbe ọhun.
Awọn ajinigbe naa sa lọ, wọn si ri kẹkẹ Napep ti wọn fi n ṣiṣẹ aburu naa gba lọwọ wọn, ṣugbọn ajọ ẹṣọ alaabo ṣifu difẹnsi ni Kwara sọ pe Yusuf tapa sofin ajọ naa pẹlu bo ṣe kuna lati gbaṣẹ ko too lọọ ṣiṣẹ naa.