Nitori to fẹẹ da awọn ileewe ijọ ẹlẹsin pada fun wọn, MURIC gbe Makinde ṣepe

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ẹgbẹ kan to n ja fun ẹtọ awọn Musulumi, Muslim Right Concern, MURIC, ti gbe Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ṣepe, wọn ni ko ni i nisinmi mọ titi ti yoo fi kuro lori apere ijọba.

Eyi ko ṣẹyin ikede ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, pe oun ti ṣetan lati da awọn  ileewe to jẹ tawọn ijọ ẹlẹsin pada fun awọn to da kaluku wọn silẹ.

Lati nnkan bii aadọta (50) ọdun sẹyin nijọba ẹkun Iwọ-Oorun Guusu orileede yii ti gba awọn ileewe to jẹ pe awọn ijọ ẹsin lo da wọn silẹ, to si gba gbogbo akoso lori wọn kuro lọwọ awọn ẹlẹsin naa gbogbo.

Lara iru awọn ijọ bẹẹ la ti ri Catholic, Baptist, Saint Peter, Saint Paul, Saint Mary, Saint Theresa, Anwar-Ul-Islam, Ansar-Ud-Deen, Islaideen ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, ni gomina ipinlẹ Ọyọ kede pe ijọba oun ti ṣetan lati da awọn ileewe naa pada fawọn ijọ to jẹ olowo wọn latilẹ wa.

Ṣugbọn lọjọ keji, iyẹn Satide to kọja yii, l’Alaaji Ishaq Akintọla ti i ṣe oludari ẹgbẹ MURIC ta ko ipinnu ijọba yii, to si bẹrẹ si i gbe gomina ṣepe, to si n dukooko mọ ọn pe niṣe lawọn yoo fibo le e danu nile ijọba.

Gẹgẹ bo ṣe sọ ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin, o ni “Bi Gomina Makinde ṣe n gbero lati da awọn ileewe ti ijọba ti gba lọwọ awọn ijọ ẹlẹsin lati aadọta (50) ọdun sẹyin yii, ko ni i foju ba oorun mọ titi ti yoo fi kuro nile ijọba, nitori gbogbo ọna ta a ba mọ labẹ ofin la fi maa ta ko o.

“Makinde ti mọ pe awọn ijọ ẹsin Kirisitẹni lo ni eyi to pọ ju ninu awọn ileewe wọnyi, iyẹn lo ṣe fẹẹ gbe igbesẹ to gbe yii lati le fiya jẹ awọn Musulumi.

“Awọn ileewe ta a si n sọ yii naa, nnkan ajumọni gbogbo araalu ni, nitori ijọba amunisin awọn oyinbo, to jẹ pe ajiyinnrere ni wọn, lo dọgbọn ẹtan gba ilẹ lọwọ awọn Musulumi lati fi da awọn ileewe wọnyii silẹ. Lẹyin ti wọn pari awọn ileewe yii tan ni wọn sọ wọn lorukọ ijọ Kristẹni.

“Lẹyin naa ni wọn fi oju oloore awọn Musulumi to fun wọn nilẹ gun igi pẹlu bo ṣe jẹ pe gbogbo awọn Musulumi to lọ sibẹ si awọn ileewe wọn yii ni wọn sọ di Kirisitẹni pẹlu tipatipa.

Nigba naa ni wọn bẹrẹ si i kọ lati gba awọn Musulumi si awọn ileewe naa tabi ki wọn sọ wọn di Kirisitẹni ni tipatipa. Iyẹn lọmọ Musulumi to n jẹ Rasheed ṣe di Richard, wọn sọ Isiaq di Isaac; Ibraheem, di Abraham; Yusuf, di Joseph; Maryam di Mary ati bẹẹ bẹẹ lọ.

“Gbogbo eeyan to ba mọ Makinde daadaa yoo ti mọ pe ifẹ inu awọn ẹgbẹ ọmọlẹyin Jesu nikan lo fẹẹ maa ṣe. O waa n fi awọn Musulumi to n jẹ labẹ ẹ ninu ijọba boju lati tẹ ẹtọ awọn Musulumi gidi mọlẹ. Nitori iru iwa bayii lo ṣe yọ igbakeji rẹ to jẹ Musulumi gidi nipo, to si fi eyi to kan n jẹ orukọ Musulumi lasan rọpo rẹ.

“Lati ọjọ ti Makinde ba ti da awọn ileewe ijọba pada fawọn ijọ ẹlẹsin la ti maa gbogun ti i pẹlu gbogbo ohun ta a ba mọ nilana ofin, ko si ni i nisinmi mọ titi ti yoo fi kuro nile ijọba”.

Leave a Reply