Nitori to fẹsun pe o n kowo sapo ara ẹ kan Dapọ Abiọdun, wọn da alaga kansu yii duro

Jamiu Abayọmi

Alaga kansu kan lẹkun ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ijẹbu, Họnọrebu Wale Adedayọ, ni wọn ti da duro bayii pe ko lọọ rọkun nile fun oṣu mẹta, titi ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun ṣiṣe owo ilu kumọkumọ ti fi kan an.

Bamubamu ni sẹkẹtariati naa kun laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ yii, fun ọlọpaa ati awọn agbofinro loriṣiiriṣii, lasiko ti ijokoo ile n lọ lọwọ lori aṣẹ ti gomina pa pe ki wọn yẹ aga mọ ọmọkunrin naa nidii lori ẹsun ajẹbanu ti wọn fi kan an.

Ọkunrin naa lo ti kọkọ kọwe ẹsun meji ọtọọtọ si ajọ to n ri si ṣiṣe owo ilu mọkumọku, iyẹn Ecomonic Financial Crimes Comission (EFCC), ati ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, Independent Corrupt Practices Commission (ICPC),  lọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọgbọnjọ, oṣu yii, nibi to ti fẹsun kan Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun pe ko ti i san kọbọ si apo iṣuna ijọba ibilẹ naa lati bii ọdun meji sẹyin, ati pe gbogbo ẹtọ to yẹ ko maa tẹ ijọba ibile naa lọwọ lati ọdun meji sẹyin ni gomina naa n gbẹsẹ le. Bẹẹ lo ni aisan awọn owo to yẹ ati awọn ajẹmọnu gbogbo yii lo fa a ti ẹgbẹ APC ko fi rọwọ mu daadaa lasiko eto idibo to kọja yii.

Lasiko ijokoo tawọn kansẹlọ ṣe lori alaga kansu naa,  lawọn kansẹlọ meje ti tọwọ bọwe lori iyọkuro alaga wọn.

Awọn kansẹlọ naa ni Faṣeyi Adesuji to n ṣoju Itele, Wọọdu keje, Boluwatifẹ Oṣunfisan, to n ṣoju Imuṣin, Wọọdu keji, Kẹmi Aliu, to n ṣoju Wọọdu kẹwaa ni Imobi, Adeniyi Adenuga, to n ṣoju Wọọdu kin-ni, ni Imuṣin, Abass Sidikat, to n ṣoju Owu, Wọọdu karun-un, Biyi Oguntubọ, to n ṣoju ẹkun kẹsan-an ni Imobi, ati Rotimi Williams, to n ṣoju ẹkun Ajebandele, Wọọdu kọkanla. Gbogbo wọn ni wọn jọ panu pọ ni ki Adedayọ lọọ rọkunle na, ko si yọju si ijokoo ile-igbimọ aṣofin kansu naa ti yoo tun waye lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.

Ọkan-o-jọkan ẹsun ni wọn fi kan alaga naa, leyii ti wọn ṣakojọ sinu iwe ẹsun to tẹ awọn oniroyin lọwọ l’Ọjọbọ Tọside, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii, ti wọn si paṣẹ fun akapo ati ẹni to wa nidii eto isuna ni kansu naa lati mu gbogbo ẹda iwe bi owo ṣe wọle ati bo ṣe jade ninu asunwọn ijọba ibilẹ naa lọwọ lasiko ipade ọhun.

Bakan naa ni wọn paṣẹ fun alaga yii pe ko ko gbogbo ẹru atawọn nnkan to ni i ṣẹ pẹlu kansu naa fun igbakeji rẹ, ki iyẹn si maa ṣakoso lọ gẹgẹ bi ofin orileede wa tọdun 1999 ṣe la a kalẹ.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan an ni gbigba miliọnu mẹrin Naira(N4M) ninu akanti ijọba ibilẹ lati fi ṣe ironilagbara ti ko waye lọdun 2022, fifi owo to n lọ bii miliọnu meji Naira (N2M) ṣofo lori ayẹyẹ ayajọ ọdun Iṣẹṣe tọdun 2022, bibaana ẹgbẹrun lọna ọtalenigba Naira (N260.000)  gẹgẹ bii owo ti alaga atawọn lọgaalọgaa ni kansu naa fi ṣabẹwo kaakiri loṣu Kẹfa ọdun 2023 yii.

“Bakan naa lo tun ko owo kan to jẹ ẹgbẹrun lọna igba ataabọ Naira (N250,000) ti wọn ni wọn fi ṣabẹwo kaakiri pẹlu awọn lọgaalọgaa lọ siluu Abẹokuta. Nina owo kan to din diẹ lẹẹẹdẹgbẹta Naira (N426,000)  ti wọn fi pese abọ eto inawo ayẹyẹ ọdun ibilẹ Jigbo, to waye ni Ila-Oorun Ijẹbu lọdun 2020, ko too di pe wọn yan alaga naa sipo rara. Wọn lo tun gba owo kan to jẹ ẹgbẹrun lọna ọtalelọọọdunrun din mẹwaa Naira (N350,000) ti wọn la kalẹ lati naa si ayẹyẹ awọn obinrin to n kopa ninu oṣẹlu ijọba ibilẹ naa lọdun 2022, ti ko si ko owo naa silẹ fun ẹgbẹ ọhun”.

Awọn ẹsun jibiti owo kikona ti wọn fi kan alaga naa pọ lọlọkan-o-j’ọkan. Lara rẹ tun ni ẹgbẹrun lọna ọtalelọọdunrun din mẹwaa Naira (N350,000)  mi-in ti wọn lo na lasiko ti wọn n ṣe ifilọlẹ ile awọn aṣofin kansu naa ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2023 yii. Lori ifilọlẹ naa lo tun baana ẹgbẹrun lọna ọdunrun Naira din diẹ (N295,000) mi-in le. Bakan naa lo tun loun fi miliọnu mẹjọ Naira le diẹ (N8.2M) kan aga ati teburu ogun fun awọn ọmọ ile-iwe.

“Ko tan sibẹ o, o tun gba  ogun miliọnu (N20M) Naira ti ijọba ipinlẹ Ogun fi ranṣẹ si apo iṣuna ijọba ibilẹ to n ṣe alaga fun, eyi ti wọn ni wọn ko mọ bi owo naa ṣe rin. Bẹẹ ni wọn lo tun na miliọnu mẹẹẹdoogun Naira (N15M) mi-in lati ọdọ ijọba ipinlẹ yii kan naa. Wọn lo tun jẹ awọn ọdẹ ti ileeṣẹ ALGON n ṣoju fun lowo lati bii oṣu marun-un sẹyin, ati aimọye owo bẹẹ bẹẹ lọ.

Iwe ẹsun naa ni wọn kadii rẹ nlẹ pe, “Pẹlu gbogbo ẹsun ti a ka si i lẹsẹ yii, ki Họnọreebu Wale Adedayọ ṣi yẹba na fun oṣu mẹta gbako, ka le raaye ṣewadii to peye lori awọn ẹsun naa.

Lẹyin eyi ni wọn sun ijokoo si Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun yii.

 

Leave a Reply