Monisọla Saka
Kayeefi lọrọ ọkunrin kan to fi agbegbe abule Garki, niluu Abuja, ṣebugbe, Adamu Habib, ṣi n jẹ fawọn to gbọ pe nitori ṣingọọmu lo fi dero ẹwọn. Ọkunrin ẹni aadọta ọdun (50) naa, nile-ẹjọ Upper Area Court, Abuja, ti ju sẹwọn oṣu mẹrin bayii latari ṣingọọmu paali meji to ji gbe.
Wọn ni ebi ipapanu buruku ọhun ko pa a de idi burẹdi tabi irẹsi, ṣingọọmu ti ijẹkujẹ ẹ ti i si naa lo ran an nibi ti ko fẹ. Bo tilẹ jẹ pe ọdaran naa rawọ ẹbẹ sile-ẹjọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun naa, ṣugbọn o ni ki wọn ṣiju aanu wo oun.
Agbefọba, Ọlarewaju Ọshọ, ṣalaye fun ile-ẹjọ pe olupẹjọ, iyẹn Joseph Sunday, ti ile itaja igbalode Faxx Supermarket, Abuja, lo waa fẹjọ ọdaran naa sun lagọọ ọlọpaa Durumi, lọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Alaye to ṣe fun wọn ni pe lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni Ọgbẹni Adamu wọnu ile itaja awọn wa, ko si ri nnkan mi-in ji tayọ idi meji ṣingọọmu ‘Orbit’, pali meji, ti owo ẹ jẹ ẹgbẹrun lọna mejila ati ojilelẹgbẹrin Naira(12,840).
Ọshọ tẹsiwaju pe lasiko tawọn n ṣe iwadii ati ifọrọwanilẹnuwo, ni ọdaran yii jẹwọ pe loootọ loun ji ṣingọọmu gbe, ṣugbọn ki wọn ṣaanu oun. Ẹṣẹ to ṣẹ yii lo sọ pe o ta ko abala ọrinlenigba ati meje (287) iwe ofin ilẹ wa.
Eyi lo mu ki Adajọ Ishaq Hassan, faaye beeli ẹgbẹrun mẹwaa Naira(10,000) silẹ fun Adamu lasiko to n ṣedajọ ọrọ naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, o si fa a leti lati jawọ ninu iwa eeri palapala bẹẹ.
Bakan naa ni adajọ tun pa a laṣẹ fun un lati san ẹgbẹrun mejila ati ojilelẹgbẹrin Naira, (12,840) gẹgẹ bii owo itanran nnkan to ji.
Lẹyin alaye aṣoju ijọba, ti ọdaran ko si lanfaani lati san owo itanran ati beeli ti wọn faaye ẹ silẹ fun un ni adajọ ran an lẹwọn oṣu mẹrin.