Nitori to ji pọnmọ gbe lọja, adajọ ju Yusuf sẹwọn

Adewale Adeoye

Iwaju adajọ ile-ẹjọ ‘Sharia Court’ kan, Onidaajọ Umar Lawal Abubakar, to wa lagbegbe Tukuntawa, nipinlẹ Kano, ni wọn wọ Ọgbẹni Abdulwahab Yussuf, ẹni ọdun mẹtalelogun lọ.

Ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan an ni pe o ji ẹran pọnmọ kan to jẹ ti Abilekọ Auwal Fatihu. Eyi ti wọn sọ pe apapọ owo ohun to ji jẹ ẹgbẹrun mẹjọ aabọ Naira.

ALAROYE gbọ pe ọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni Yusuff to n gbe lagbegbe Tukuntawa, yọ kẹlẹkẹlẹ wọnu isọ oniṣowo ọhun, to si ji ẹran pọnmọ onitọhun gbe sa lọ.

Loju-ẹsẹ ti iṣẹlẹ naa ti waye ni Auwal ti lọ si teṣan ọlọpaa kan to wa laduugbo Fagge, to si lọọ fẹjọ Yusuf sun nibẹ. Awọn ọlọpaa ọhun ni wọn lọọ fọwọ ofin mu un nile, ti wọn si foju rẹ bale-ẹjọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

Ọlọpaa olupẹjọ, Insipẹkitọ Abdullah Wada, to foju Yusuff bale-ẹjọ sọ niwaju adajọ naa pe ẹsun meji ni wọn fi kan an. Akọkọ ni pe o lọ sinu isọ ti ki i ṣe tiẹ, to si lọọ ji ọja nibẹ. Ẹsun keji ni pe o lọọ ji ẹran pọnmọ oniṣowo kan. Awọn ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan Yusuff yii ni ọlọpaa agbefọba ni o lodi sofin ipinlẹ Kano.

Gbara ti wọn ka awọn ẹsun ọhun si i leti tan loun paapaa ti gba pe loootọ loun jẹbi won, to si ni ki adajọ ile-ẹjọ yii ṣiju aanu wo oun lori ọrọ naa.

Adajọ Lawal Abubakar ni ki wọn lọọ fi I pamọ sọgba ẹwọn. Lẹyin naa lo sun igbẹjo si ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii.

 

Leave a Reply