Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni mọlẹbi kan ti a mọ si Animọsaun, niluu Ilọrin, wọ ọmọ wọn, Sọdiq Abdulraman, lọ siwaju adajọ Lawal Ajibade, ni kootu ibilẹ kan niluu Ilọrin ipinlẹ Kwara, fẹsun pe ọmọ naa lo oogun oloro.
Mọlẹbi sọ fun ile-ẹjọ pe ṣe ni Abdulraman n kẹgbẹ-kẹgbẹ, to si n lo oogun oloro, wọn ni ko kọsẹ ọwọ, o kọ jalẹ, wọn tun gbe e lọ si ọgba ti wọn ti le ṣe atunṣe fun un, o ni oun ko le duro nibẹ. Wọn waa rọ ile-ẹjọ ko paṣẹ pe ki wọn gbe ọmọ naa lọ si ọgba atunṣe kọ ma le rin papọ pẹlu awọn to n ba rin mọ, ko le wulo fun ara rẹ lọjọ ọla.
Adajọ beere lọwọ Abdulraman pe ṣe loootọ ni o maa n lo oogun oloro, o dahun pe loootọ ni oun maa n mu igbo ati Tiramadọ. O o fi kun un pe ọgba atunṣe ti wọn gbe oun lọ ko yatọ si ọgba ẹwọn, ati pe awọn oju toun n ri ninu ọgba naa lo n ba oun lẹru fun idi eyi ibẹ ko le rọrun foun lati maa gbe.
O tẹsiwaju pe oun fẹ ki adajọ beere lọwọ wọn pe osu meloo ni yoo lo ni ọgba atunṣe naa abi oun yoo maa gbe ibẹ lọ titi laelae ni?
Adajọ beere lọwọ ọkan lara osisẹ ọgba atunse to wa sile-ẹjọ pe oṣu meloo ni wọn fẹ ko lo, ṣugbọn iyẹn fesi pe ọdun kan ati aabọ ni wọn maa n lo, ati pe ko si ẹru kankan to yẹ ko ba a tori pe awọn eeyan bii tiẹ naa ni wọn ko sibi kan naa, tawọn si maa n fun wọn ni ounjẹ asiko bii irẹsi, ẹwa, sẹmo ati bẹẹ bẹẹ lọ, ṣugbọn to ba tete gbọ ibawi, o le ma lo to ọdun kan aabọ ti yoo fi maa lọ sile wọn.
Adajọ pasẹ loju-ẹsẹ pe ki wọn lọọ fi Abdulraman si ọgba atunṣe fun ọdun kan, titi ti iyatọ yoo fi wa, ti ko si ni i ri awọn ẹruuku ti wọn dijọ n lo oogun oloro mọ, eyi ni yoo jẹ ko wulo fun ara rẹ ati mọlẹbi lọjọ iwaju.