Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ootọ lowe Yoruba to ni oloootọ ki i lẹni, owe yii lo ṣẹ mọ ọga agba ajọ ẹṣọ oju popo nipinlẹ Kwara, Federal Road Safety Commission (FRSC), Frederick Ogidan, lara pẹlu bi wọn ṣe yọ ọ danu bii jiga nibi iṣẹ nitori ododo ọrọ to sọ lori owo iranwọ epo ti ijọba apapọ yọ, eyi to mu ki ilu le koko mọ awọn ọmọ Naijiria lara.
ALAROYE, gbọ pe lọjọ keji ti Frederick Ogidan, ṣọrọ naa nibi eto kan to waye ni Fasiti Al-hikmah, niluu Ilọrin, pe yiyọ owo iranwọ epo ti iṣejọba Aarẹ Bọla Tinubu yọ ti mu inira nla ba gbogbo ọmọ Naijiria pata, ati pe o mu ipalara ba bi ajọ ẹṣọ alaabo ojupopo ṣe n ṣiṣẹ jake-jado Naijiria, nitori pe gbogbo nnkan lo gbowo lori.
O tẹsiwaju pe owo iranwọ epo yiyọ ọhun ko ipalara ba eto iṣuna ajọ naa, nitori pe alekun de ba owo tawọn n na, ti ko si jẹ ki wọn le maa ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bii iṣẹ nipa gbigbe mọto kiri lọ sibi to yẹ lati lọọ ṣiṣẹ, fun idi eyi, oun n reti ki wọn fi kun owo isuna to n wọle fun wọn nipinlẹ Kwara, ki lilọ bibọ awọn le maa rọrun.
Ọrọ ti Ogidan, sọ yii lo da wahala si i, lagbada ti wọn fi yọ ọ nipo lati olu ileeṣẹ ajọ naa niluu Abuja, wọn ni ọrọ to naa ta ko ofin ati ilana FRSC, ti wọn si fi ẹlomiiran rọpo rẹ loju-ẹṣẹ.
Owuyẹ kan sọ fun ALAROYE pe S.E Dawulung, ni wọn fi ranṣẹ si Kwara bayii lati waa rọpo Ogidan, gẹgẹ bii ọga ajọ ẹṣọ alaabo ojupopo tuntun.
Ọkan inu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa to ba akọroyin wa sọrọ ni bonkẹlẹ ni ijọba Tinubu yii ko yatọ si ijọba ologun to jẹ ari-i-gbọdọ-wi, ikun imu baale ni wọn. Wọn ni ko sohun to buru ninu gbogbo ohun ti ọkunrin sọ lasiko ifọrọwerọ naa, nitori ko sirọ ninu awọn alaye to ṣe. Ṣugbọn eyi ti ijọba iba fi gba ẹbi wọn, ki wọn si ṣatunṣe nibi to yẹ, niṣe ni wọn yọ ọkunrin naa nipo, eyi to lodi si eto ijọba awa-ara-wa ta a ni a n ṣe bayii.