Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Awọn akanṣẹ mọto mẹwaa ati ọkada ogun (20) ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, fi ta ikọ alaabo to gbe kalẹ lati ri si rogbodiyan awọn Fulani ati agbẹ nilẹ Yewa, lọrẹ lọjọ Iṣẹgun, ọjọ keji, oṣu kẹta ọdun yii.
Nigba to n fa awọn mọto ati ọkada naa fun ikọ yii nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun naa, Gomina Abiọdun ṣalaye pe ipin akọkọ yii yoo lọ si Ariwa Yewa, Guusu Yewa ati Imẹkọ-Afọn ti awọn Fulani ti n ṣoro ju.
O fi kun un pe ipese awọn nnkan wọnyi, ati awọn eelo ibanisọrọ, jẹ ọna kan to n tọka ẹ pe eto aabo jẹ ijọba oun logun gan-an. Abiọdun sọ pe bẹẹ loun yoo maa tẹsiwaju ninu ohun gbogbo ti yoo mu alaafia ba ipinlẹ Ogun, oun yoo si maa gbogun ti iwa ọdaran gbogbo.
Nigba to n kin ọrọ gomina lẹyin, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun, dupẹ lọwọ Gomina Dapọ Abiọdun. O ni pẹlu iranlọwọ bii eyi, iṣẹ yoo ya awọn ẹṣọ alaabo lara lati ṣe, wọn yoo si le tete maa kapa awọn oniṣẹ ibi nipinlẹ yii.