Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti bu ẹnu atẹ lu gomina banki apapọ ilẹ wa, Godwin Emefiele, latari wahala tawọn araalu n koju lori ọrọ owo Naira tuntun.
O ni ọrọ naa ti da wahala ti ko ṣee fẹnu sọ silẹ lorileede Naijiria, ati pe ṣe lo yẹ ki wọn ṣeto ti awọn araalu yoo fi lanfaani si owo Naira tuntun yii pẹlu irọrun.
Ọba Akanbi sọ siwaju pe wahala ipaarọ owo naa ti mu ki eto ọrọ-aje dẹnukọlẹ, to si ti ṣakoba nla fun awọn olokoowo, idi niyẹn to fi yẹ ki igbesẹ bẹrẹ lori amojuto pinpin owo naa.
Ninu atẹjade kan ti Kabiyesi fi sita nipasẹ akọwe iroyin rẹ Alli Ibrahim, lo ti sọ pe ṣe ni gbogbo awọn igbesẹ naa wa lati tabuku awọn iṣẹ rere ti Aarẹ Muhammed Buhari ti ṣe.
O ke si awọn tọrọ kan, paapaa, ijọba apapọ, lati tete wa nnkan ṣe lori wahala ọrọ ipaarọ owo Naira, eyi to ti sọ ọpọ eeyan di alailọkọ, to si n febi pa wọn.
Oluwoo ni ọrọ naa ko yọ awọn lọbalọba silẹ rara, o parọwa si awọn aṣofin lati ṣe ofin alagbara kan pe ki banki apapọ ilẹ wa ṣafikun ọjọ ipaarọ owo yii, ki wọn si ko owo naa jade lọpọ yantuuru.
O ni o yẹ ki Emefiele tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ orileede Naijiria fun inira to ko ba wọn lori ọrọ owo Naira tuntun yii, ko si sọ idi ti ko fi si owo to pọ niluu.