Ọrẹoluwa Adedeji
Ọba Muslim Abiọdun Ogunbọ, Ogudu Ọṣhadi ti ilu Ọgọmbọ, nijọba ibilẹ Eti-Ọsa, nipinlẹ Eko, ti fi aidunu rẹ han si iya ti ko ṣee fẹnu sọ to n jẹ awọn araalu lori wahala ti wọn n koju nibi ọrọ owo tuntun tijọba ṣẹṣẹ paarọ tawọn eeyan naa ko ri gba, ati ọwọngogo epo bẹntiroolu to tun gbode kan, eyi to mu ki ohun gbogbo gbowo lori.
Ọba alaye yii kọminu si ọro epo bẹntiroolu to di imi eegun, eyi ti ko jẹ ki eto ọrọ aje wa lọ bo ṣe yẹ, to si mu ki ọpọ nnkan ti mẹkunnu n jẹ di ohun ti apa wọn ko ka mọ.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Keji yii, ni Kabiyesi sọrọ naa ninu atẹjade to gbe sita, eyi to tẹ ALAROYE lọwọ.
Ọba ilu Ọgọmbọ, to wa nijọba ibilẹ Eti Ọsa, nipinlẹ Eko, ni, ‘‘Ojoojumọ ni aafin mi n kun fawọn ero ti wọn n waa fi ẹdun ọkan wọn lọlọkan-o-jọkan han lori bi gbogbo nnkan ṣe n lọ lasiko yii. Bo tilẹ jẹ pe mi o wo wọn niran gẹgẹ bii ọba alaye, ṣugbọn omi to ba kere leeyan maa n rẹla si ni ọrọ naa. Aanu awọn eeyan mi ṣe mi, o si jẹ ẹdun ọkan fun mi lati maa wo wọn niru ipo ti wọn wa yii.
Ọpọ obi ni ko rowo ra ounjẹ fun awọn ọmọ, awọn ọlọja ko ri ọja ta nitori awọn ti yoo raja ko ri owo gba ni banki ti wọn fi le ra ohun ti wọn ba fẹ. Awọn to saisan ko rowo roogun, ọpọ idile ni ọrọ owo ti ko si yii si ti fẹẹ daru bayii, nigba ti ọkọ ko ri owo ṣe ojuṣe rẹ ninu ile’’.
Nigba to n sọrọ nipa awọn oniṣowo keekeekee ti ọrọ owo Naira naa ṣakoba fun, Ọba Abiọdun ni, ‘ko si iṣẹ niluu, awọn iṣẹ keekeeke ti awọn mẹkunnu tun fi n dọgbọn ara wọn lo tun n parun lọ pẹlu wahala owo tuntun yii. Ọpọ awọn ọmọ wa lo n ṣowo POS, ti wọn fi n gbọ bukaata ẹbi wọn, awọn to n ta ata, gaari atawọn owo pẹẹpẹẹpẹ bẹẹ ni ọrọ owo tuntun yii ti ṣakoba fun. Ta o ba si ni i purọ, awọn mẹkunnu ni ọrọ yii kan ju.
‘‘Ohun to mu ọrọ naa baayan ninu jẹ ni pe ki i ṣe pe awọn eeyan yii n lọọ tọrọ owo ni banki, owo ti wọn fi oogun oju wọn ko jọ lo di ọran fun wọn lati gba nileefowopamọ yii’’.
Ọba Abiọdun koro oju si bi ijọba ko ṣe tun wa nnkan ṣe si ọrọ epo bẹntiroolu to di ọwọngogo ti ko ṣee ra, ti inira si n re lu ara wọn fun awọn eeyan ilu. ‘O ṣe ni laaanu, o si baayan lọkan jẹ, lati gbọ pe awa la n ṣe epo nilẹ wa, ọkan ninu awọn ohun alumọọni ti Ọlọrun fi kẹ wa nilẹ yii ni, ṣugbọn inira ni epo naa jẹ fun awọn ọmọ Naijiria bayii.
‘‘Nigba teeyan ba fi wakati bii mẹẹẹdogun to sileepo, iru iṣẹ wo ni iru ẹni bẹẹ fẹẹ ṣe to ba pada de ọfiisi tabi ibi to ti n ṣiṣẹ. Epo to wọn yii ti sọ awọn ounjẹ ti a mọ si ounjẹ mẹkunnu bii ẹwa, gaari, ata ati bẹẹ bẹẹ lọ di ohun ti apa wọn ko ka mọ, eyi buru jai, o si yẹ ki awọn to wa nibi eto isakoso ilẹ wa ṣe amojuto eleyii.
O waa rọ olori banki apapọ ilẹ wa, Godwin Emefiele, ati Aarẹ Buhari pe ki wọn pe koto, ki wọn pe koto, ki wọn tun ero wọn pa lori awọn ipinnu wọn lori ọrọ owo tuntun naa. O rọ wọn ki wọn ko owo naa jade lọpọ yanturu, ki wọn si wa ọna abayọ si ọrọ epo bẹntiroolu to gbowo lori. Ọba Ogunbọ ni ki wọn tete ronu ọna ti wọn yoo gbe gbogbo eto naa gba ti yoo fi mu irọrun ba awọn mẹkunnu.
‘‘Mo rọ ijọba ki wọn ma duro de igba ti awọn araalu ba fọn jade, ti wọn n fi ẹhonu han, eyi ti ko le mu eeso rere jade, ti yoo si tun da wa pada sẹyin fun ọpọlọpọ ọdun’’.
Kabiyesi ni, ‘‘ara n kan araalu, a si gbọdọ dena ohunkohun to le mu ki ikanra naa tun pọ si i tabi to le mu ki wọn woju ijọba, nitori were sun, were sun, bi were ba sun kan ogiri, yoo kọju si ẹni to ni ko maa sun lọ ni.’’ Bẹẹ ni Ọba ilu Ọgọmbọ pari ọrọ rẹ.