Nitori wahala pipaarọ owo atijọ si tuntun, awọn ọdọ binu dana sun banki kan

Faith Adebọla

 Ọkan ninu awọn ẹka ileefowopamọ Access Bank, to wa niluu Warri, ipinlẹ Delta, ti jona. Awọn ọdọ ti wọn n fẹhonu han ni wọn fibinu dana sun banki ọhun ni nnkan bii iyalẹta Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji yii, wọn lawọn o fara mọ aṣẹ ile-ẹjọ to ga ju lọ lori gbedeke nina owo atijọ ati tuntun papọ. Ati pe ẹtan to n waye lori ọrọ ipaarọ owo tuntun naa ti su awọn, inira ati idaamu tawọn n koju rẹ ti pọ ju ẹmi awọn lọ.

Ẹnikan tọrọ naa ṣoju rẹ lo ya fidio iṣẹlẹ ọhun, to si ju u sori ẹrọ ayelujara, lori ikanni tuita “sabiboiharry rẹ, lọjọ Wẹsidee yii. Fidio naa ṣafihan ina ọmọ ọrara to ti ran mọ orule banki ọhun, to si ti mu awọn waya ati awọn nnkan ẹṣọ banki naa.

Onitọhun kọ ọ sabẹ fidio naa pe: “O ṣẹlẹ! Ifẹhonuhan to lagbara ti n waye ni Warri o, lagbegbe Udu, lori bi CBN ṣe paṣẹ ki wọn ma gba owo atijọ lọwọ awọn eeyan mọ. Wọn ti dana sun banki Access o, o ti n jona gidi.”

Lasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ, Alaroye gbọ pe awọn oṣiṣẹ alaabo ati ti ileeṣẹ panapana nipinlẹ ọhun ti lọ sibi iṣẹlẹ naa, iṣẹ aṣelaagun si ti n lọ nibẹ lati daabo bo owo, dukia atawọn oṣiṣẹ banki naa.

Bakan naa la gbọ pe awọn agbofinro ti lọọ ya bo awọn oluwọde naa lati pẹtu si wọn lọkan.

Tẹ o ba gbagbe, titi dasiko yii ni awọn araalu n binu, ti wọn koro oju si inira ati ijakulẹ ti eto pipaaro owo Naira atijọ si tuntun yii mu ba wọn, paapaa lẹnu ọjọ mẹta yii.

Eyi ko ṣẹyin gbedeke ọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ti banki apapọ ilẹ wa ta ku pe nina owo atijọ naa gbọdọ wa sopin, bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ giga ju lọ ni ki wọn ṣi mọwọ ro lori ẹ na.

Ọpọ araalu ni ko ri owo tuntun naa gba, bẹẹ si lawọn banki kan atawọn olokoowo ti n kọ owo atijọ naa sawọn to ni i lọwọ lọrun, eyi to tubọ mu ki ka-ra-ka-ta nira laarin ilu.

Iwọde ati ifẹhonuhan yii ko mọ si ipinlẹ Delta nikan o, ọrọ naa ti n lọ kari kari. Bi ifẹhonu han ṣe n lọ lọna marosẹ Eko si Abẹokuta, nibi tawọn ọdọ gbegi dina si lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ati lọjọ Wẹsidee pẹlu, bẹẹ lawọn tinu n bi n ṣewọde n’Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, awọn tipinlẹ Ondo naa ko si gbẹyin, wọn n ṣewọde ni Ọwọ ati Akurẹ.

Bakan naa lọrọ si ri niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara

Leave a Reply