Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gomina ipinlẹ Ondo Rotimi Akeredolu ti kede ofin konilegbele niluu Igbara-Oke to jẹ ibujoko ijọba Ifẹdọrẹ latari rogbodiyan to fẹẹ su yọ lẹyin atundi eto idibo sipo kansẹlọ to waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Asẹ yii waye ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin gomina, Richard Ọlabọde, fi ṣọwọ sawọn oniroyin lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Agbẹnusọ gomina ọhun ni ijọba gbe igbesẹ yii lati dena rogbodiyan to ṣee ṣe ko waye ninu ọkan-o-jọkan ifẹhonu han tawọn eeyan tinu n bi gun le ẹyin ti wọn kede ẹni to jawe olubori ninu atundi ibo naa.
Arakunrin waa rọ gbogbo awọn ọba atawọn olori agbegbe kọọkan lati mojuto agbegbe ti wọn n ṣakoso, ki wọn si ri i daju pe awọn eeyan wọn tẹle ofin konilegbele oni wakati mẹrinlelogun ọhun.
Ajọ eleto idibo ipinlẹ Ondo ni wọn fagi le eto idibo kansẹlọ wọọdu mẹta nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ ati Ifẹdọrẹ latari wahala to waye lawọn wọọdu ọhun lasiko ti wọn n dibo ijọba ibilẹ ninu osu kẹjọ, ọdun to kọja.
Ọjọruu, Wẹsidee, ni atundi idibo naa waye, ti ajọ to ṣeto rẹ si ti fawọn mẹtẹẹta to yege niwe-ẹri l’Ọjọbọ, Tọsidee ọsẹ yii.