Idowu Akinrẹmi, Ikire
Gomina ipinlẹ Ọsun, Isiaq Gboyega Oyetọla tun ti kede konilegbele miiran lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide, ti i ṣe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa, yii kaakiri ipinlẹ Ọṣun. Gomina ni oun gbe igbesẹ naa lẹyin ipade pajawiri lori eto aabo ipinlẹ naa. O ni igbesẹ yii waye latari bi awọn janduku kan ṣe n ko dukia onidukia, ti wọn si tun n da alaafia ilu ru. Ko ni i si lilọ bibọ ọkọ ati ọkada fun ẹnikẹni, afi awọn ti iṣẹ wọn ba ṣe pataki lasiko konilegbele naa.