Faith Adebọla, Eko
Adajọ Ademọla Adesanya ti ile-ẹjọ Majisreeti to wa lagbegbe Ọjọọ ti paṣẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, pe tawọn lanlọọdu meji, Lawal Abubakar, ẹni ogoji ọdun, ati Chuks Okoye, ẹni ọdun mejilelọgọta, ti wọn ko wa siwaju oun ko ba ti kaju beeli toun fun wọn, ki wọn sọ wọn sahaamọ ọlọpaa titi di ọdun to n bọ ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju lori ẹsun pe wọn fi tipatipa ko ẹru tẹnanti kan, Ọgbẹni Sunday Kọmọlafẹ, sita, lọwọ ara wọn.
Ba a ṣe gbọ, wọn lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii, lawọn afurasi ọdaran mejeeji huwa ti wọn tori ẹ foju wọn bale-ẹjọ ọhun.
Agbefọba ASP Simeon Uche to ṣoju fun olupẹjọ ṣalaye nigba ti wọn foju awọn afurasi mejeeji ọhun bale-ẹjọ fun igba akọkọ pe niṣe lawọn lanlọọdu mejeeji yii jọ pawọ-pọ lọọ ko ẹru Ọgbẹni Kọmọlafẹ kuro ninu yara kan to rẹnti, eyi to wa ni Ojule karun-un, Opopona Tẹdi, lagbegbe Ọjọọ, nipinlẹ Eko, wọn ni tẹnanti jẹ owo ile gọbọi, ko si kuro nile awọn, eyi to mu kawọn lanlọọdu naa lọọ fibinu ko ẹru ẹ sita lai sọ fun ẹlẹru tabi gba iyọnda rẹ, lọkunrin naa fi lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa, wọn si mu wọn.
Agbefọba ni iwa buruku lawọn lanlọọdu naa hu, o ni niṣe ni wọn sọ ara wọn di agbofinro ọsan gangan, ti wọn n da sẹria to wu wọn fun ayalegbe wọn, eyi to lo ta ko iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko, ni isọri ojilelọọọdunrun (340) ati irinwo le mejila (412).
Nigba ti wọn beere boya wọn jẹbi tabi wọn o jẹbi, awọn olujẹjọ mejeeji lawọn ko jẹbi.
Adajọ Ademọla ni ọjọ kẹwaa, oṣu ki-in-ni, ọdun 2022, ni igbẹjọ to kan maa too waye, ṣugbọn oun faaye beeli silẹ fawọn lanlọọdu mejeeji ọhun pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọtalenigba naira (N250,000) fun ọkọọkan wọn, wọn si tun gbọdọ wa oniduuro meji meji ti ọkọọkan wọn ni iye owo kan naa lakaunti rẹ, bẹẹ lawọn ati oniduuro wọn gbọdọ pese iwe-ẹri owo-ori wọn.
O ni ti wọn o ba kaju awọn nnkan toun ka silẹ wọnyi, ki wọn ṣi lọọ maa gbatẹgun ni ahamọ ọlọpaa na.