Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ileeṣẹ ọmọ ologun to wa ni bareke Sobi, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti fi ṣọja to lu nọọsi meji lalubami nileewosan ijọba to jẹ talabọọde kan lagbegbe Okekere, sahaamọ, lẹyin to lu awọn nọọsi naa tan fẹsun pe wọn ni ko lọọ ra eroja ti wọn yoo fi gbẹbi fun iyawo rẹ wa.
ALAROYE gbọ pe lasiko tawọn nọọsi meji naa n gbẹbi fun iyawo ṣọja yii lọwọ ni wọn ni ko lọọ ra awọn eroja igbẹbi bii ibọwọ ati nnkan miiran ti wọn yoo lo wa, ṣugbọn ṣe ni ṣọja ọhun kagidi bori pe oun ko ni i ra eroja kankan tori pe ijọba ti pese gbogbo ohun to yẹ ni ileewosan naa, to si bẹrẹ si i lu awọn nọọsi naa nilu bara.
Alukoro ileeṣẹ ọmọ ogun ni bareke Sobi, niluu Ilọrin, St. Sgt Waziri, sọ pe awọn ti mu ṣọja naa, o si ti wa lahaamọ, awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọmọ ogun si ti bẹrẹ iwadii lẹkun-un-rẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.
Alaga ẹgbẹ awọn nọọsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Alaaji Shehu Aminu, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ṣalaye pe ṣọja ọhun lo gbe iyawo rẹ to loyun lọ si ileewosan ijọba kan to wa ni agbegbe Okelele, nibi ti wọn ti ṣeto igbẹbi fun un, nigba ti wọn gbe e wọ yara igbẹbi ti wọn si ni ki ọkọ rẹ lọọ ra eroja igbẹbi wa lo
Fariga, to sọ pe gbogbo owo to yẹ ni ijọba ti pese sileewosan naa, to si bẹrẹ si i lu awọn nọọsi meji to n tọju iyawo rẹ lalubami. O tẹsiwaju pe awọn nọọsi naa ti n gba itọju nileewosan bayii, ti ṣọja naa si ti wa ni ahamọ fun iwadii to peye.