Idunnu ti ṣubu lu ayọ bayii fun gbogbo ọmọ Naijiria bayii pẹlu bi ijọba apapọ ṣe fun ileeṣẹ ifọpọ ti ọkan pataki ninu awọn oniṣowo ilẹ wa, Alaaji Aliko Dangote da silẹ lanfaani bayii lati maa fọ epo bẹntiroolu ti a oo maa ri lo nilẹ wa.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu yii, ni ọkunrin oniṣowo yii sọ ọ di mimọ nigba to n fi igo ti epo bẹntiroolu wa ninu rẹ han lori tẹlifiṣan. Dangote ṣalaye pe epo to daa, to si kun oju oṣuwọn ni, o si le figa gbaga pẹlu awọn epo bẹntiroolu ti wọn n pese kaakiri agbaye.
Inu oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni ileeṣẹ Dangote ti kọkọ kede pe awọn yoo bẹrẹ si i pese epo bẹntiroolu ọhun, ko too di pe wọn tun sun un siwaju.
Ni bayii ti ileeṣẹ to n mojuto iye ti wọn n ta epo nilẹ yii ati l’Oke-Okun, ti ni ajọsọpọ ọrọ pẹlu ileeṣẹ to n pese epo nilẹ wa, (NNPCL), ALAROYE gbọ pe agba bẹntiroolu bii miliọnu mẹẹẹdọgbọn ni ileeṣẹ ifọpo Dangote yoo maa pese lati inu oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, nigba ti yoo ba si fi di inu oṣu Kẹwaa, ọdun yii, afikun yoo ba epo ti wọn n pese naa, yoo si di miliọnu lọna ọgbọn.
Ṣinkin ni inu awọn araalu n dun, ti wọn si n sọ pe pẹlu bi ileeṣẹ Dangote ṣe fẹẹ bẹrẹ si i pese epo yii, adinku yoo de ba inira ti araalu wa n koju lori epo bẹntiroolu.
Tẹo ba gbagbe, fa-a-ka-ja-a loriṣiiriṣii lo ti wa laarin ijọba atawọn alagbara kan, gbogbo agbara ni wọn si sa lati ri i pe Dangote ko pese epo. Ṣugbọn bi ọn ṣe n gba ọtun yọ ni Dangote naa n gba osi yọ si wọn, Lẹyin-o-rẹyin, ọkunrin oniṣowo naa rẹyin gbogbo aọn ọta rẹ, ni bayii, ileeṣẹ rẹ yoo bẹrẹ si i pese epo bẹntiroolu fun Naijiria.