Nnkan de, araalu koju ija sawọn oṣiṣẹ LASTMA l’Ekoo eyi lohun to fa a

Adewale Adeoye

Fun bii wakati mẹta ni wahala, idarudapọ ati laaṣigbo nla fi bẹ silẹ ni Abule Ẹgba, to wa nijọba ibilẹ Alimọṣọ, nipinlẹ Eko, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kọkanla, ọdun yii. Ṣe lọrọ di bo o lọ yago fun mi lọna lasiko tawọn araalu kan tinu n bi lagbegbe ọhun kọju ija sawọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ loju titi nipinlẹ naa, iyẹn ‘Lagos State Traffic Management Authority (LASTMA), nitori ti wọn fẹsun kan wọn pe awọn ni wọn ṣokunfa bi dẹrẹba mọto aladaani kan ṣe pade iku ojiji lọjọ ọhun.

ALAROYE gbọ pe awọn oṣiṣẹ LASTMA ọhun atawọn ọlọpaa ni wọn n lọ kaakiri lagbegbe ọhun lati fọwọ ofin mu awọn onimọto akero ati awọn aladaani gbogbo ti wọn ba lu ofin irinna.

Lasiko naa ni wọn fọwọ ofin mu dẹrẹba mọto Toyota Corolla kan pe o gba oju ọna mọto BRT kọja, wọn si fẹẹ wọ ọ lọ sileeṣẹ wọn. Gbogbo ẹbẹ ti dẹrẹba naa n bẹ wọn pe ki wọn ṣaforiji foun ni ko wọ wọn leti. Nigba ti ẹbẹ naa pọ ju ni wọn ba sọ fun un pe ko lọọ wa ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira wa kawọn le ju u silẹ, ṣugbọn ti dẹrẹba naa sọ pe ogoji ẹgbẹrun pere lowo to wa lọwọ oun.

Nigba tawọn oṣiṣẹ ajo naa ko gba ni dẹrẹba naa ba sọ pe oun maa san ẹgbẹrun lọna aadọrin Naira. Awọn oṣiṣẹ ajọ naa sọ pe ko lọọ gbowo naa jade wa fawọn lọdọ oni POS. Nibi ti wọn ti n sọrọ lọwọ ni dẹrẹba mọto akero kan toun naa lu ofin irinna, ti ko si fẹẹ bọ sọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ naa ti lọọ kọ lu dẹrẹba mọto Toyota Corolla naa nibi to duro si, loju-ẹsẹ ni oloogbe naa ti ku, bẹẹ ni aburo rẹ ti wọn jọ wa ninu mọto naa ṣeṣe gidi. Iṣẹlẹ ọhun lo bi awọn ọdọ agbegbe ọhun ninu ti wọn fi tu sita lati fẹhonu han ta ko ohun tawọn oṣiṣẹ LASTMA naa ṣe.

Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa teṣan agbegbe naa ti wọn waa pẹtu sawọn ọdọ naa ninu ni ọrọ yii ko ṣe le ju bẹẹ lọ, nitori pe wọn ti fẹẹ bẹrẹ si i da wahala silẹ laarin ilu lọjọ naa. Awọn kọọkan ninu wọn ti bẹrẹ si i da ina soju titi ibi tawọn mọto BRT maa n gba kọja. Ti wọn si n sọ pe awọn maa bawọn oṣiṣẹ ajọ naa fa wahala gidi.

Ṣa o, ori lo ko awọn oṣiṣẹ LASTMA naa yọ lọjọ yii, nitori pe gbara ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ lawọn paapaa ti na papa bora.

Leave a Reply