Nnkan de! Awọn afẹmiṣofo ti ya wọ awọn igbo kaakiri ilẹ Yoruba

Ọlawale Ajao, Ibadan

Bi ijọba ko ba tete wa nnkan ṣe si i, o ṣee ṣe ki awọn agbesunmọmi ya wọ awọn igboro ilu gbogbo kaakiri ilẹ Yoruba, ki wọn maa pa awọn araalu, ki wọn si maa ji wọn gbe.
Eyi le ri bẹẹ nitori bi awọn janduku agbebọnrin ṣe ya wọ ipinlẹ Ọyọ atawọn ipinlẹ mi-in nilẹ Yoruba, ti wọn si fara pamọ sinu igbo lawọn agbegbe kan ni ipinlẹ naa.
Awọn fijilante, iyẹn ẹgbẹ awọn ọdẹ ibilẹ ni ipinlẹ yii, iyẹn Vigilante Group of Nigeria (VGN) ni wọn fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Adari ẹgbẹ VGN nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Ogunmakin Moses, fidi ẹ mulẹ pe ọpọlọpọ igbo to yi ipinlẹ Ọyọ atawọn ipinlẹ mi-in ka lawọn janduku agbebọn ti wa bayii pẹlu awọn ohun ija oloro.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ọpọ igba lapa wa ki i ka awọn eeyan yii nitori ibọn ti wọn gbe lọwọ lagbara pupọ ju tiwa lọ.
“Ọlọrun ṣe e, ofin gba wa laaye lati maa lo nnkan ija lati koju awọn ọdaran, ṣugbọn aini nnkan ija igbalode n fa wa sẹyin gidi gan-an lati le koju awọn ọdaran lati dena iṣẹ ibi ọwọ wọn”.
O waa rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati pese ibọn ati nnkan ija fawọn ọdẹ ibilẹ ki wọn le rohun le awọn afẹmiṣofo naa kuro nilẹ yii.

Leave a Reply