Nnkan de, awọn agbebọn ji ọmọ ogun ilẹ wa gbe, miliọnu mẹwaa ni wọn n beere

Monisọla Saka

Ọmọ ogun oju ofurufu ilẹ wa kan, Nigerian Air Force (NAF), ACM Shuaibu Umar Bashir, ti bọ sọwọ awọn agbesunmọmi ajinigbe kan lasiko to n pada sẹnu iṣẹ ẹ nipinlẹ Niger. Lọjọ Aiku Sannde, ogunjọ oṣu yii, ni awọn ajinigbe naa gbe Shuaibu wọgbo lọ, loju ona Birnin Gwari, nipinlẹ Niger.

Ọjọ mẹta pere ni wọn ni awọn ọdaju ẹda yii fun awọn mọlẹbi Shuaibu, lati san miliọnu mẹwaa Naira, ti wọn ba  fẹẹ ri ọmọ wọn laaye ati alaafia.

Ninu ọrọ ti ọkan ninu awọn mọlẹbi Shuaibu ba ileeṣẹ Sahara Reporters sọ lo ti ni, “Latigba tiṣẹlẹ naa ti waye lọjọ Aiku, Sannde, ogunjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni awọn alaṣẹ ọmọ ogun oju ofurufu atawọn ileeṣẹ ologun ilẹ wa ti kọ lati ba awọn mọlẹbi sọrọ, wọn ko tilẹ mẹnu le ọrọ naa bo ti wu ko mọ. Ẹnu iṣẹ lo wa tiṣẹlẹ buruku yii fi ṣẹ si i, o n pada sibi ti wọn pin in si lati wọ iṣẹ ni lọjọ to kagbako awọn eeyan naa.

Ipinlẹ Niger niṣẹ gbe e lọ, ṣugbọn oju ọna Birnin Gwari, laarin ipinlẹ Niger nibẹ naa, ni wọn ti ji i gbe lọ.

Lati ọjọ Sannde ti ọrọ yii ti waa ṣẹlẹ ti ọkan gbogbo ẹbi ti wa loke, a ko ri akitiyan kan sàn-án lori ọna lati gba a silẹ latọdọ awọn ileeṣẹ ologun”.

Bakan naa ni ileeṣẹ ologun oju ofurufu ilẹ Naijiria ti ọkunrin ti wọn ji gbe yii n ṣiṣẹ labẹ ẹ gan-an ko ti i kede pe wọn ji ọkan lara awọn gbe, tabi ilakaka kankan lori bi ọkunrin naa yoo ṣe gba idande ki ọjọ mẹta tawọn atilaawi da too pe

Leave a Reply