Faith Adebọla
Tiyanu-tiyanu ladajọ atawọn ero to wa ni kootu fi n wo baale ile kan, Kazeem Yẹkinni, pẹlu bo ṣe figbe ta lasiko to n rojọ ni kootu kọkọ-kọkọ kan to wa ni Mapo, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, nibi to wọ iyawo rẹ, Abilekọ Ọpẹyẹmi, lọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2023, to si n rawọ ẹbẹ sile-ẹjọ naa pe ki wọn ba oun fopin si ajọṣepọ lọkọ-laya to wa laarin awọn, tori igbeyawo naa ti su oun patapata, iyawo oun ti fẹẹ yọ ile aye lẹmi-in oun.
Baale ile yii sọrọ, ilẹ kun, nigba to n ṣalaye ohun tiyawo rẹ n ṣe fun un lọọdẹ rẹ. O ni, “Oluwa mi, inira ti ko ṣee maa fẹnu sọ niyawo ti mo fẹ n mu ba mi. O ti baye mi jẹ patapata.
“Ṣe ti epe ojoojumọ to maa n ṣẹ fun mi ni ki n sọ ni, abi ti ọrọ kobakungbe to maa n sọ si mi ṣaa? O ti sọ mi di igba ikolẹ rẹ, mi o si ja mọ kinni kan loju awọn aladuugbo atawọn ọrẹ mi, tori ko sibi ti ko ti le yẹyẹ mi ni gbangba, o si ti leri pe oun maa ba mi lorukọ jẹ kanlẹ nigboro Ibadan yii ni koun too dẹyin lẹyin mi.
“Lọjọ ti kinni ẹ ba jẹun, niṣe lo maa fi kọkọrọ ti mi pa mọ’nu yara, ko si ni i jẹ ki n raaye lọ sibi iṣẹ ounjẹ oojọ mi. O digba tinu ẹ ba rọ ko too ṣi mi silẹ, ninu ile ti mo fowo mi haaya.
Ọjọ mi-in, o le jẹ kọkọrọ mọto mi lo maa siisi. Lọjọ kan, niṣe lo lọọ pe awọn ẹṣọ Amọtẹkun si mi pe ki wọn lu mi daadaa, to si pa oriṣiiriṣii irọ mọ mi.”
Nigba t’adajọ beere boya awọn mọlẹbi wọn gbogbo gbọ nipa ọrọ yii, ọkunrin naa fesi pe: “Awọn mọlẹbi mi lawọn ko le ba mi da si i, tori ẹru ẹ n ba awọn. O ti sọ ara ẹ dẹrujẹjẹ gidi ni o.”
Nigba ti Abilekọ Ọpẹyẹmi maa rọjọ tiẹ, ko jiyan rara lori awọn ẹsun ti ọkọ rẹ ka silẹ, ko si sọ pe o purọ mọ oun, ohun to ṣaa n tẹnumọ fun adajọ ni pe ki wọn ma ṣe tu awọn ka, oun ko ṣetan lati kuro lọọdẹ ọkọ oun, ki wọn fawọn laaye lati lọọ yanju ọrọ naa nitunbi-inubi nile.
O ni, “Oluwa mi, ko too kẹjọ wa sọdọ yin yii, mo ti bẹ ẹ titi ninu ile, ko gbẹbẹ mi ni o. Ẹ jẹ ki n tun lọọ bẹ ẹ daadaa si i.
“Amọ to ba loun ko gbẹbẹ, a jẹ pe kẹ ẹ ṣe nnkan to loun n fẹ, ṣugbọn ọdọ mi ni kẹ ẹ paṣẹ pe kawọn ọmọ wa o.”
Ṣa, Onidaajọ S. M. Akintayọ, ti sọ pe ko si igbeyawo to bofin mu laarin awọn mejeeji lati ibẹrẹ, tori ẹ, ko si nnkan tile-ẹjọ fẹẹ tu ka. O ni ki kaluku maa lọ lọtọọtọ, ki ọmọ kan ṣoṣo ti wọn bi wa lọdọ iyawo, o si paṣẹ ki baale ile naa maa san ẹgbẹrun mẹwaa Naira loṣooṣu fun itọju ọmọ.