Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oṣiṣẹ ajọ sifu difẹnsi kan ti wọn ti n fi ọpọlọpọ ọjọ wa ni wọn ti ba oku rẹ ninu kanga kan lagbegbe Aduramigba, ni Ido-Ọṣun, nipinlẹ Ọṣun bayii.
Ọmọkunrin ti wọn porukọ rẹ ni Sọdiq yii, lo n ṣiṣẹ pẹlu ajọ sifu difẹnsi nipinlẹ Eko, ṣugbọn ti awọn mọlẹbi rẹ wa nipinlẹ Ọṣun.
ALAROYE gbọ pe lati ọjọ Aiku, Sunday, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni Sodiq ti di awati nipinlẹ Ọṣun, ti awọn mọlẹbi ataladugbo si ti daamu pupọ lori ẹ.
Ṣugbọn nigba to di ọjọ Tọsidee lẹnikan lọ sidii kanga kan ti ko jinna sibi to n gbe, bo ṣe si i lo n wo oku Sodiq ninu ẹ, to si pariwo pe kawọn araadugbo waa wo nnkan ti oun ri.
Awọn araadugbo la gbọ pe wọn lọọ fi ọrọ naa to ileeṣẹ ajọ sifu difẹnsi agbegbe naa leti, awọn yẹn ni wọn si gbe oku rẹ jade latinu kanga ọhun.
Ni kete ti iwadii bẹrẹ lori iku abami naa la gbọ pe wọn ri foonu rẹ gba lọwọ ẹnikan, eleyii to ran wọn lọwọ lati fi pampẹ ofin gbe afurasi meji.
Ajọ yii kọ jalẹ lati sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe wọn ti taari ẹjọ naa sọdọ awọn.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘Ko pẹ ti wọn taari ẹjọ naa sọdọ awa ọlọpaa, a ti bẹrẹ iṣẹ lori ẹ, bẹẹ ni iwadii si ti bẹrẹ loju-ẹsẹ’