NNPCL ti tun fi kun owo epo bẹntiroolu, eyi niye ti wọn n ta a bayii

Ọrẹlouwa Adedeji

Lẹyin bii ọsẹ mẹta ti wọn ṣẹ bẹẹ gbẹyin, ileeṣẹ to n ri sọrọ epo bẹntiroolu nilẹ wa, (NNPCL) ti tun kede pe awọn ti fowo kun iye ti awọn ọmọ Naijiria yoo maa ra jala epo kan bayii.

Ni bayii, ẹgbẹrun kan ati Naira mẹẹẹdọgbọn (1,025) ni ileesẹ NNPCL yoo maa ta epo nipinlẹ Eko bayii, ti wọn si ti bẹrẹ si i ta a bẹẹ. Ṣugbọn ẹgbẹrun kan ati ọgbọn Naira ni awọn ileeṣẹ alagbata epo yooku n ta a. Eleyii yatọ si ẹgbẹrun kan din Naira meji ti ileeṣẹ NNPC n ta a tẹlẹ, ti awọn ileeṣẹ epo yooku si n ta a lowo to le ni ẹgbẹrun kan Naira fun jala kan.

Ẹgbẹrun kan ati aadọta Naira (1, 050), ni ileeṣẹ NNPCL to wa ni Abuja yoo maa ta jala epo kan, lati ẹgbẹrun kan ati ọgbọn Naira ti wọn n ta a tẹlẹ. Ni gbogbo awọn agbegbe bii Kuje, oju ọna Airport atawọn agbegbe kaakiri ni wọn ti yi mita epo wọn si owo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ kede yii.

Ẹgbẹrun kan ati ọgọta Naira lawọn ileeṣẹ epo aladaani yooku yoo maa ta epo tiwọn, eyi ti wọn si ti bẹrẹ si i ta a bẹẹ latigba ti ikede yii ti waye.

Ọpọ awọn araalu ni wọn ti n kọminu lori inira ati wahala ti owo epo to n lọ soke lojoojumọ yii ti n ko ba wọn, bẹẹ ni wọn bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa, eyi ti wọn ni o ti ṣakoba fun ọrọ aje wọn.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii ni ileeṣẹ Dangote kede pe ko nilo ki ileeṣẹ elepo ilẹ wa yii tun maa ra epo nilẹ okeere, o ni awọn ni anito ati aniṣẹku ti ọmọ Naijiria le lo, eyi ti yoo din wahala atawọn inawo lilọ ra epo nilẹ Okeere ku.

ALAROYE gbọ pe o ṣee ṣe ki wọn tun fi kun owo epo naa laipẹ rara.

 

Leave a Reply