NSCDC Kwara ti doola ẹmi akẹkọọ Fasiti Kogi ti wọn ji gbe

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹta, oṣu Kejila, ọdun 2024 yii, ajọ ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, fi iroyin ayọ lede pe awọn ti doola ẹmi Fauziyah Muhammad, akẹkọọ Fasiti ipinlẹ Kogi, to wa ni Anyingba, tawọn ajinigbe ji gbe kuro ni akata awọn ajinigbe ọhun layọ ati alaafia lai fara pa.

Ọga agba ajọ ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Umar Muhammed, fi lede ni ọjọ Aje, Mọnnde, ọsẹ yii, lo ti fi idi ọrọ naa mulẹ pe awọn ti doola ẹmi Fauziyah layọ ati alaafia, kọda, awọn yoo fi Fauziyah ranṣẹ sipinlẹ Kogi, laipẹ.

O tẹsiwaju pe awọn olugbe agbegbe Ajégúnlẹ̀, Egbejila, niluu Ilọrin, ni wọn kẹẹfin awọn Fauziyah, ihooho ni wọn ri ọmọbìnrin yii, ti wọn si ta awọn ẹṣọ alaabo lolobo ti wọn fi lọọ gbe ọmọ akẹkọọ yii tawọn si fun un laṣọ.

O fi kun un pe Fauziyah ni oun ko mọ bi oun ṣe de ipinlẹ Kwara lati Kogi, o ni oun to ri mọ ni pe iwe tòun mu lọwọ ja bọ, tòun si fẹẹ mu un, ṣugbọn oun ko mọ ohun to n ṣẹlẹ mọ titi ti oun fi yaju siluu Ilọrin.

Umar, ni awọn ti fi ọrọ naa to Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrazaq, leti tawọn yoo si fi akẹkọọ naa ṣọwọ si ipinlẹ Kogi.

Tẹ o ba gbagbe, lọṣẹ to kọja yii lawọn ajinigbe ṣowo ọhun ji Fauziyah, akẹkọọ Fáṣítì Kogi, to wa ni ipele kẹrin (400 level), ni ẹka ẹkọ imọ nipa ede Gẹẹsi (English) gbe niluu Anyingba, nipinlẹ Kogi, ti awọn ajinigbe naa si waa ja a ju silẹ niluu Ilọrin.

Wọn ni Fauziyah ko le ṣọrọ daadaa mọ latari awọn idojukọ to ti ri lọwọ awọn ajinigbe ọhun.

Leave a Reply