Ọlawale Ajao, Ibadan
Yoruba bọ, wọn ni ìbọn lápátí kò lápátí, ta ló jẹ́ gbà kí wọ́n dojú ìbọn kọ òun. Bẹẹ lọrọ ri fun obinrin oniṣowo kan, Shakirat Ọlaogun, ẹni to kegbajare pe ọkọ oun, Akinọla Ọlaogun fẹẹ da asiidi soun ati iya oun lara, ṣugbọn tọkunrin naa sọ pe oun fi omi buruku to maa n paayan ọhun ba wọn ṣere ni.
Ọlaogun yii kan naa lo jẹwọ pe loootọ loun maa n na iyawo oun ni gbogbo igba nitori pe ki i gbọrọ si oun lẹnu. Ṣugbọn o ni ki ile-ẹjọ ma ṣe tu igbeyawo awọn ka gẹgẹ bi iyawo oun ṣe n fẹ.
Ọkunrin to fi adugbo Owode Academy, n’Ibadan, ṣebugbe yii sọ pe “Loootọ ni mo fẹẹ da asiidi si oun atiya ẹ lara, ṣugbọn mo kan fi halẹ mọ ọn lasan ni, nitori iwa agbere to n hu. Ohun to ṣe da bii ẹni pe mo maa n lu u naa niyẹn.
“Ni nnkan bii ọsẹ marun-un sẹyin ni mo ṣọ ọ dele ọkunrin to n yan lale. Niṣe niyawo mi ko awọn ọmọ mi kuro nile ti wọn jọ n sun ile ale ẹ.”
Ṣaaaju niyawo ẹ, Shakirat Ọlaogun, ti rọ kootu ibilẹ Ọja’ba to wa ni Mapo, n’Ibadan, lati fopin si ibaṣepọ ọlọdun mejila to wa laarin oun atọkọ, o lojoojumọ lọkunrin naa maa n lu oun, bẹẹ lo maa n tu ibi ti oun maa n fowo pamọ si, to si maa n ji oun lowo ko lọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Mi o le sọ iye igba to ti ji mi lowo. Ọpọ igba ti mo ba ti lọ si ṣọọbu lo maa n ja ilẹkun ibi ti mo n kowo si, igba to ba mowo to kere ju lo maa n mu ẹgbẹrun marun-un Naira (N5,000), nigba mi-in gan-an, o le mu ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn Naira (N25,000).
“Lọjọ kan lo fẹẹ da asiidi si emi atiya mi lara, o loun maa pa wa patapata.”
Olujẹjọ ko ja iyawo ẹ niyan ni kootu, o ni loootọ loun maa n lu u nitori ki i gbọrọ soun lẹnu, ati pe o jẹ obinrin kan to fẹran ọkunrin ju bo ṣe yẹ lọ.
Adajọ kootu ọhun, Oloye Ọdunade Ademọla, ti fopin si igbeyawo naa, o waa yọnda ọmọ wọn meji akọkọ fun olupẹjọ, o si paṣẹ fun baba wọn lati maa san egbẹrun mẹwaa Naira fun iya wọn loṣooṣu gẹgẹ bii owo ounjẹ wọn.