Adebiyi Adefunkẹ, Abẹokuta
Dokita Ọladunni Ọdẹtọla ati Nọọsi Bamgboṣe tawọn ajinigbe ji l’Ọjọruu Wẹsidee, ọsẹ to kọja, yii, lójú ọna Abẹokuta s’Imẹkọ, ti gba itusilẹ, alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ti i ṣe ọjọ kejila, oṣu kẹrin yii, ni wọn gba ominira.
Balogun Isalẹ ilu Ìmẹ̀kọ, Oloye Ganiu Akinloye, to jẹ ki ominira dokita ati nọọsi yii di mimọ, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe, loootọ lawọn ti wọn ji gbe naa gba itusilẹ lalẹ Mọnde. O ni awọn ajinigbe naa yọnda wọn fun ilu lọwọ alẹ.
Bo ṣe dupẹ lọwọ Ọlọrun lo dupẹ lọwọ Gomina Dapọ Abíọ́dún, Balogun dupẹ lọwọ Onimẹkọ pẹlu awọn eeyan to polongo ijinigbe ọhun lori ẹrọ ayelujara. Ṣugbọn nipa boya owo ni wọn sàn ki wọn too ri wọn gba pada bayii, Balogun ko mẹnu lọ sibẹ rara.
Ẹ oo ránti pe nigba ti Dokita Ọdẹtọla, olori ọsibitu Jẹnẹra Imẹkọ, ati Nọọsi Bamgboṣe n lọ ninu mọto Camry to jẹ ti dokita yii lawọn kan yọ si wọn lojiji labule Olubọ, ti wọn ko wọn wọgbo lọ tibọn tibọn lọjọ Wẹsidee to kọja, ti wọn si n beere miliọnu rẹpẹtẹ ki wọn too le tu wọn sílẹ̀.
Bakan naa lo tun jẹ pe meji ninu awọn ọlọdẹ to n wa wọn kiri inu igbo, fara gbọta ibọn lọjọ diẹ lẹyin ijinigbe yii. Mọto meji àti ọkada mẹsan -an ti wọn fi n wa wọn ninu igbo lawọn ajinigbe naa si tún dana sun.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ko ti i wi nnkan kan nipa igbominira naa lasiko yii.
Boya oun naa yoo fi atẹjade sita to ba ya.