Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti ke si gbogbo awọn eeyan ipinlẹ naa lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba rẹ, ki ipinlẹ naa le goke agba.
Lẹyin ti ile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii dajọ pe oun lo jawe olubori ninu idibo gomina to waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022, nipinlẹ Ọṣun, ni gomina sọrọ yii.
A oo ranti pe ni kete tidiibo naa pari ni ẹgbẹ oṣelu APC ati ọmọ-oye wọn, Alhaji Adegboyega Oyetọla gbe Sẹnetọ Adeleke, ẹgbẹ PDP ati ajọ eleto idibo INEC lọ sile-ẹjọ.
Ni kootu akọkọ (Tribunal), meji lara awọn onidaajọ mẹta ti wọn gbọ ẹjo naa sọ pe adiju ibo wa ninu idibo naa, eleyii ti wọn ni o lodi si ofin eto idibo.
Nitori idi eyi, wọn ni Oyetọla lo ni ibo to pọ ju lẹyin ti awọn fagi le awọn ibudo ti adiju ibo ti waye, wọn ni ki ajọ INEC gba satifikeeti lọwọ Adeleke, ki wọn si fun Oyetọla.
Ṣugbọn nigba ti ẹjọ naa de ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, owọ osi ni wọn fi yi idajọ Tiribuna danu, wọn ni ko si ẹri kankan to fidi rẹ mulẹ pe adiju ibo wa.
Oyetọla ati APC gba ile-ẹjo to ga ju lọ lọ, awọn onidaajọ marun-un ti Onidaajọ Agim jẹ alaga fun si sọ lojọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun yii, pe ifasikoṣofo patapata ni ẹjọ ti Oyetọla pe Adeleke.
Kootu ni ẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ rara, bẹẹ ni ẹlẹrii ti Oyetọla pe ko lagbara lati jẹrii fun un nitori oṣiṣẹ ijọba labẹ Oyetọla ni. Nitori naa, wọn yi ẹjọ naa danu, wọn si kede pe ki Gomina Adeleke maa ba iṣẹ rẹ lọ.
Ṣe ni ariwo ayọ gba gbogbo ipinlẹ Oṣun kan nigba ti wọn gbọ nipa idajọ naa. Niluu Ẹdẹ, tilu-tijo ni wọn fi n dawọọdunnu lọdọ gomina.
Nigba to n sọrọ lori idajọ naa, Gomina Adeleke dupẹ lọwọ Ọlọrun, awọn mọlẹbi rẹ, ẹgbe oṣelu PDP, awọn adajọ ti wọn di ododo mu ati awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun fun aduroti wọn.
O ni idajọ naa fihan pe ohunkohun to ba ti jẹ ifẹ Ọlọrun ko ṣee bajẹ rara. O ni o han gbangba pe awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun finnu-findọ dibo fun oun, bẹẹ ni Ọlọrun tun ti ipinnu awọn araalu lẹyin
O waa sọ pe oun ko le da iṣẹ naa ṣe, oun nilo ifọwọsowọpọ awọn araalu, bẹẹ lo si tun ṣeleri pe oun ko ni i ja wọn kulẹ.
Lara awọn ti wọn ti ranṣẹ ikini ku oriire si gomina ni Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla to jẹ gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ. Oyinlọla ni ile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii ti fi ohun (voice) awọn araalu han, eyi ti i ṣe ohun Ọlọrun.
O ṣeleri lati tubọ maa ṣatilẹyin fun gomina ati igbakeji rẹ, Kọla Adewusi, o si rọ awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati gbagbe ọrọ idibo, ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu Adeleke ati ijọba rẹ.