Faith Adebọla, Eko
Inu ẹni ki i dun keeyan pa a mọra, ẹni ba ri ọkan lara awọn irawọ oṣere tiata ilẹ wa nni, Biọla Adebayọ, ti inagijẹ rẹ n jẹ Eyin Ọka, tabi keeyan wo fidio to gbe sori atẹ ayelujara Instagiraamu ẹ, ko ṣẹṣẹ digba ti wọn ba sọ fun tọhun pe inu idunnu ati ayọ gidi lọmọbinrin naa wa lasiko yii ko too mọ. Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹrin, yii, lo kuro lẹgbẹ awọn apọn-binrin, o dẹni to n ni ade lori, o di ẹni ile ọkọ pẹlu igbeyawo alarinrin.
Ninu fidio kan to ṣafihan oun pẹlu ọkọ rẹ tuntun naa, nibi ti wọn ti n ka ẹjẹ igbeyawọ niwaju kọmiṣanna kootu, Biọla kọ ọ sabẹ fidio naa pe: “A kuu oriire igbeyawa wa, ọkọ mi,… Mo sọ pe ‘Bẹẹ ni’ lonii, oni la si bẹrẹ igbe aye wa titi lae.
“Irin ajo ti wọn n pe ni igbeyawo yii, pẹlu bi mo ṣe maa n fọwọ sọya nipa ọpọ nnkan nigbesi aye, sibẹ, mi o le fọwọ sọya nipa ọrọ igbeyawo, ẹru to si n ba mi ni o jẹ ki n ti ko wọ ọ lati igba pipẹ sẹyin, ṣugbọn mo gbẹkẹ le ọrọ rẹ, mo si gbagbọ, ki i ṣe agbara mi o, ki i si ṣe okun mi, ṣugbọn mo nigbagbọ ninu ẹni to mọ ibẹrẹ ati opin (Alfa ati Omega). Idi niyẹn ti mo fi gbe ibẹru ati aniyan mi ju sẹbaa ẹsẹ Oluwa wa, Jesu. Ma a ṣe ipa temi, Ọlọrun yoo si ṣaṣepari ati aṣepe iyooku.
“Ololufẹ mi, o ṣeun to o yan mi lati ba ọ rin irinajo igbesi aye yii pẹlu ẹ, gbogbo ọkan mi ni mo fi yan ọ, iwọ lẹni akọkọ laye mi.
“Ẹ ba mi yọ, a ti bẹrẹ igba ọtun, a ti bọ soju ọna ayeraye.”
Afi bii ẹni pe awọn ololufẹ arẹwa naa ti n reti igbeyawo rẹ tẹlẹ ni, ọkan-o-jọkan ọrọ iwuri ati ikini kuu oriire lo n rọjo lori ikanni Biọla Adebayọ.
ALAROYE maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin wa fun yin laipẹ.