Oṣere ilẹ wa, Nkechi Blessing, tọrọ aforiji ni gbangba ni Toronto, lorileede Canada

Jọkẹ  Amọri

Yoruba ni bi ẹlẹjọ ba mọ ẹjọ rẹ lẹbi, ko ni i pẹ lori ikunlẹ, ọrọ yii lo ṣe rẹgi pẹlu oṣere ilẹ wa to pupa daadaa, to tun jẹ ọmọ Ibo, ṣugbọn to n ṣere Yoruba nni, Nkechi Sunday ti gbogbo eeyan mọ si Nkechi Blessing. Niṣe ni ọmọbinrin naa kunlẹ to ba ruburubu niwaju awọn oṣere ẹgbẹ ẹ niluu Toronto, lorileede Canada, to si n tọrọ aforiji lọwọ awọn agbaagba ẹgbẹ oṣere ilẹ wa, iyẹn TAMPAN pe ki wọn dariji oun. Niṣe lo kunlẹ niwaju ọga awọn onitiata patapata nilẹ Yoruba, Bọlaji Amusan, ti gbogbo eeyan mọ si Mr Latin.

Gbogbo bi Mr Latin si ti n sọ pe ko dide lori ikunlẹ lo n sọ pe ki wọn jẹ ki oun wa lori ikunlẹ beẹ. Lẹyin naa lo waa tọrọ aforiji lọwọ gbogbo awọn oṣere patapata, o ni oun tọrọ aforiji lọwọ gbogbo awọn ti oun ṣẹ ni agboole tiata. O ni iṣẹ naa lo gbe oun ga, to si mu oun di ilu mọ-ọn-ka kari gbogbo aye. Nidii eyi, oun tọrọ aforiji fun gbogbo ẹṣẹ to wu ki oun ṣẹ. Oju-ẹsẹ naa ni Mr Latin ti sọ pe awọn ti dariji i.

Lẹyin ẹbẹ yii ni oṣere to ga daadaa nni, Ọdunlade Adekọla, ṣadura fun un pe Ọlọrun ko ni i gba omi loju rẹ, o ṣadura fun un, o si ki i fun ọkan akin to ni lati ṣe iru ohun to ṣe yii.

Tẹ o ba gbagbe, ọdun 2021 ni ẹgbẹ oṣere Yoruba ti gbogbo eeyan mọ si TAMPAN jawee gbele-ẹ fun oṣere naa ati ọmọkunrin kan toun naa jẹ oṣere ti orukọ rẹ n jẹ Kẹhinde Adams, ti gbogbo eeyan mọ si Lẹgẹ. Ọrọ Baba Ijẹṣa ti wọn fẹsun kan pe o ṣe aṣemaṣe kan lọpọ awọn oṣere naa da si, eyi lo si di ohun to dija nla laarin Lẹgẹ ati Nkechi pẹlu awọn oṣere mi-in. Gbogbo bi Latin to jẹ ọga wọn si ṣe n sọ pe ẹnikẹni ninu wọn ko gbọdọ sọrọ mọ, ki wọn dakẹ, oṣere yii ko dahun, bẹẹ lo bu awọn agbaagba ẹgbẹ naa, o ni bi wọn ba yọ oun ninu ẹgbẹ, wọn ko yọ oun laye. Eyi lo mu ki awọn oloye ẹgbẹ naa fofin de e ninu ẹgbẹ naa pẹlu aṣẹ pe ẹnikẹni ko gbọdọ pe e soko ere, wọn ko si gbọdọ lọ sibi ere to ba fẹẹ ṣe.

Bẹẹ lọrọ wa to fi di ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtafinlogun, oṣu yii ti o kunlẹ, to si ba ruburubu niwaju gbogbo awọn oṣere to wa nibẹ, nibi to ti tọrọ idariji lọwọ awọn ọga TAMPAN atawọn oṣere yooku to wa nibẹ, to si ni oun miisi agbo oṣere naa.

Pẹlu ohun ti oṣere naa ṣe yiim ko sogun mọ, ko sija mọ laarin oun atawọn oṣere ilẹ wa.

Leave a Reply