Jọkẹ Amọri
Lẹyin ti wọn ṣe isin idagbere ti wọn ṣe fun un ni Catholic Church of Resturection, to wa niluu Eko, ni wọn sin gbajumọ oṣere tiata to maa n ṣere Yoruba ati Oyinbo, Racheal Oniga, si itẹ aladaani kan.
Laaarọ ni awọn ọmọ ẹbi oloogbe naa to sẹyin oku mama wọn ti ileeṣẹ agbokuu ti wọn n pe ni Omega gbe sinu ọkọ funfun balau kan, ti wọn si n jo, ti wọn n kọrin tẹle oku naa lẹyin, ti awọn ọkọ si to lọwọọwọ tẹle e.
Oluṣọagutan Rapheal Adebayọ lo gbadura fun mọlẹbi oloogbe.
Gbogbo awọn ọmọ ati mọlẹbi ni wọn sọrọ iwuri nipa oṣere naa.
Ẹni ọdun mẹrinlelọgọta ni Racheal Oniga ki iku too mu un lọ ninu oṣu keje, ọdun yii.