Faith Adebọla, Eko
Pẹlu bawọn mọlẹbi ṣe lawọn o fẹ ero nibi isinku ẹni wọn, Oloogbe Racheal Oniga, sibẹ ọgọọrọ eeyan lo pesẹ sibi ayẹyẹ isinku ti wọn ṣe fobinrin naa lọjọ Ẹti, Furaidee yii, nigba ti wọn gbe oku rẹ rele ikẹyin.
Ṣaaju isinku naa ni eto ijọsin ati iwaasu ti kọkọ waye ile-ijọsin Catholic Church of Ressurrection, to wa l’Ekoo, nibẹ ni Rẹfurẹndi agba, Raphael Adebayọ ti sọrọ iwuri nipa ọkan lara awọn irawọ oṣere ilẹ wa to doloogbe lẹni ọdun mẹrinlelọgbọn yii.
Ojiṣẹ Ọlọrun naa ni loootọ ni iku jẹ nnkan ibanujẹ nla, sibẹ o ni gbese nla kan ti gbogbo eeyan ni lati san ni, “Racheal Oniga ti san tirẹ, bo ṣe san an la fi n royin rẹ yii, gbogbo wa si gbọdọ ronu lori ohun tawọn eeyan yoo sọ nigba to ba kan kaluku wa”.
Oniwaasu naa tun rọ awọn mọlẹbi ati ọmọ oloogbe lati ma ṣe bara jẹ pupọ, ki wọn ṣe ara wọn lọkan, ki wọn si maa ranti ipa rere ti oloogbe naa ni laye ati nigbesi aye wọn.
Lẹyin iwaasu yii ni wọn gbe posi funfun to n dan bii digi, ninu eyi ti wọn ṣe oku Racheal Oniga lọjọ si. Itẹkuu to wa ni Omega Funeral Homes, lagbegbe Ojodu, l’Ekoo, ni wọn gbe oku naa lọ.
Lẹyin iwaasu ṣoki leti saare, ti wọn si kọrin idagbere ni ilana ẹsin Katoliiki, wọn rọ posi naa sisalẹ, awọn ọmọ oku feeru fun eeru, wọn fi yeepẹ fun yeepẹ pẹlu omije, lawọn alaayan-oku ba rọ yeepẹ bo oloogbe naa mọlẹ.
Ọpọ awọn oṣere tiata ni wọn pesẹ sibi eto isinku naa. Ṣe ṣaaju ọjọ yii lawọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ ti peju sibi eto aisun to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ni ile oloogbe ọhun to wa ni Magodo. Lara wọn ni Ọmọọba Jide Kosọkọ, Bọlaji Amuṣan (Mista Latin), Fẹmi Adebayọ, Iyabọ Ojo, Muyiwa Ademọla, Kunle Afọlayan, Desmond Elliot atawọn oṣere mi-in.
Ọpọ awọn oṣere naa ni wọn sọrọ nipa Racheal Oniga bii eeyan atata, wọn lo kopa rere laye ati lawujọ, wọn si ṣadura fun un.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu keje, ni Abilekọ Racheal Oniga ku lojiji, l’Ekoo, lẹyin aisan ranpẹ kan. Ọpọ ọmọ ati ọmọọmọ lo gbẹyin rẹ.