Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo ti ju olukọ ileewe girama kan, Gbenga Ayenioye ati ọrẹ rẹ toun jẹ onitiata, Tunde Amokeọja, sọgba ẹwọn lori ẹsun pe wọn fipa ba akẹkọọbinrin kan lo pọ.
Inu oṣu keji, ọdun yii, lawọn mejeeji huwa naa gẹgẹ bi iwadii ALAROYE ṣe fi han. Ṣe ni Ayenioye tan ọmọbinrin, ẹni ọdun mẹrindinlogun ọhun lọ si ile kan lagbegbe Latọna, niluu Oṣogbo, to si ba a lo pọ.
Lẹyin to halẹ mọ ọmọbinrin naa pe ko gbọdọ sọ fun ẹnikẹni lo tun sọ fun un pe oun ti ba ọrẹ oun kan to jẹ oludari ere tiata sọrọ pe ko fun un (ọmọbinrin yẹn) ni ipa pataki kan lati ko ninu ere ori itage kan to n ya lọwọ.
Ayenioye sọ fun ọmọ naa pe nipasẹ ikopa rẹ ninu ere naa, yoo lanfaani lati ri owo ko jọ fun idanwo Wayẹẹki to fẹẹ ṣe. Nigba to de Delightful Gold Hotel, to wa lagbegbe Onibuẹja, niluu Oṣogbo, ṣe ni Tunde tun ki i mọlẹ, to tun fipa ba a laṣepọ.
Lẹyin ti ọwọ ọlọpaa tẹ awọn mejeeji, ti wọn si ti kọ akọsilẹ lọdọ wọn, ni wọn foju bale-ẹjọ. Ẹsun meji ni wọn fi kan wọn.
Agbefọba, ASP John Idoko lo kọkọ bẹrẹ ẹjọ naa ki agbẹjọro kan lati ileeṣẹ to n ri si ọrọ ofin nipinlẹ Ọṣun, Bankọle Awoyẹmi, too sọ pe oun fẹẹ gba ẹjọ naa.
Awọn olujẹjọ mejeeji sọ pe awọn ko jẹbi awọn ẹsun mejeeji, bẹẹ ni agbẹjọro wọn, Bọla Abimbọla Ige, rọ ile-ẹjọ lati fun wọn ni beeli pẹlu ileri pe wọn ko ni sa fun igbẹjọ.
Majisreeti Ọpẹyẹmi Badmus paṣẹ pe ki agbefọba gbe faili ẹjọ naa fun agbẹjọro ijọba, ati pe ki awọn ọlọpaa maa ko awọn olujẹjọ lọ sọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ọjọ kẹrin, oṣu kọkanla, ti igbẹjọ yoo waye lori ọrọ beeli wọn.
Ṣugbọn bo ṣe di ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, ni agbẹjọro wọn tun wa sile-ẹjọ pe inu inira lawọn olujẹjọ mejeeji wa lọgba ẹwọn. O ni ẹwọn naa ko ba wọn lara mu rara, koda, wọn ti bẹrẹ aisan nibi ti wọn wa.
Nigba ti Adajọ Badmus beere fun iwe ileewosan to fidi rẹ mulẹ pe wọn n ṣaisan lọgba ẹwọn, agbẹjọro wọn ko ri iwe kankan fi silẹ.
Adajọ ni ko saaye lati fun wọn ni beeli lai ti i pe ọjọ ti oun ti kọkọ sun igbẹjọ wọn si, iyẹn ọjọ kẹrin, oṣu kọkanla, ọdun yii.