Oṣere yii ti bẹbẹ o: Funkẹ Akindele, jọwọ, dariji mi, ọmọde lo ṣe mi

Monisọla Saka

Ọkan lara awọn oṣerebinrin ilẹ wa, Juliana Ọlayọde, to gbajumọ ninu ipa Toyọsi tabi ‘Toyọ bebí’, to ko ninu ere ọlọsọọsẹ ‘Jenifa’s diary, ti gbajumọ oṣerebinrin onitiata nni, Funkẹ Akindele, tọpọ eeyan mọ si Jenifa n ṣe lawọn ọdun diẹ sẹyin, ti tọrọ idariji lọwọ Funkẹ to pe ni Anti ati ọga ẹ nigba kan ri. O ni aimọkan ati ọmọde to ṣe oun lo mu k’oun ṣiwa-hu, to fi di pe awọn pin gaari.

Bo tilẹ jẹ pe Funkẹ Akindele lo gbe obinrin ti ẹnikẹni ko mọ tẹlẹ yii jade, to sọ ọ di irawọ oṣere ninu ere, lojiji ni ija bẹ silẹ laarin wọn, owo si ni wọn lo ṣokunfa ede aiyede ọhun.

Latigba naa ni Juliana ko ti ba Funkẹ ṣe mọ, ti ki i si i fi bẹẹ han ninu awọn ere tawọn oṣere n gbe jade mọ.

Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni obinrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn yii gba ori  Instagraamu rẹ lọ. Nibẹ lo ti ni ẹmi dari oun lati bẹ Funkẹ, koun si tọrọ fun idariji ẹṣẹ lọwọ rẹ ni ojutaye, iyẹn lori ẹrọ ayelujara. Juliana ni oun ko lakaka, bẹẹ loun ko ṣe wahala koun too di ẹni taye mọ, ọpẹlọpẹ Ọlọrun ati Funkẹ naa si ni. O fi kun un pe ọpọ eeyan to ti wa lẹnju iṣẹ naa fun igba pipẹ ko lanfaani lati tete moke gẹgẹ bo ṣe ṣẹlẹ sohun lasiko toun n ba Funkẹ Akindele ṣere.

Ninu ọrọ to kọ yii lo ti ṣalaye idi to ṣe pa ere ọlọsọọsẹ naa ti, ti ko fi wo o mọ, to si tun bẹ Funkẹ pe aimọ bi wọn ṣe n ṣe lagboole tiata lo ti oun toun fi kọ lu u.

O ni, “Gẹgẹ bii ọdọmọbinrin ti ko ti i pe ogun ọdun, irinajo ere ṣiṣe mi nidii iṣẹ tiata bẹrẹ, nibi tawọn ti wọn ti fori ṣe, fọrun ṣe, ti wọn si ti pẹ nidii iṣẹ naa n gbero pe kawọn de. Abi bawo ni ọgbẹri, ẹni ti wọn ṣẹṣẹ n mu mọna ṣe le gbọrẹgẹjigẹ ninu sinnima to n milu titi, ti ki i baa ṣe iṣẹ iyanu Ọlọrun.

‘‘Ninu ọrọ temi, aanu ati oju rere Ọlọrun fara han, nitori ki i ṣe pe wọn kan gbe mi jade ṣaa lasan, ọrẹ ati igbakeji ẹni to kopa ju lọ, to jẹ gbajumọ taye n fẹ, to si ti fi ọpọlọpọ ọdun ṣiṣẹ, ni mo ṣe ninu ere ọhun ti mo fi di gbajumọ.

“Ọlọrun lo lo Anti Funkẹ Akindele, lati gbe mi jade. Koda, iyalẹnu nla lo jẹ femi gan-an alara, agaga pẹlu ọjọ ori ti mo wa, to jẹ pe ko pẹ ti mo jade ileewe girama nigba naa. Iru okiki ti mo ni pẹlu ipa Toyọsi ti mo ko ninu fiimu ọlọsọọsẹ Jẹnifa’s Diary yẹn buhaaya, o pọ ju oye mi lọ.

‘‘Amọ ai ti i mọ alude ati apade bi wọn ṣe n ṣe nidii iṣẹ tiata pada n ti mi nitikuti, pẹlu ọkunrin manija mi to jẹ pe oun naa ko mọ bi nnkan ṣe n lọ lagbo tiata, gbogbo nnkan to ba ro tabi to ba sọ nigba naa lemi maa n fara mọ lai ja a niyan.

“Afi bo ṣe di pe ọkunrin to n tọ mi sọna, to si tun n ṣe manija mi yii fi atẹjiṣẹ ranṣẹ sileeṣẹ Scene one TV, to jẹ ti Anti Funkẹ, atawọn alaṣẹ Sitcom, ti mi o si le sọ pe gbogbo nnkan to kọ sibẹ ye mi titi di akoko yii.

‘‘Mi o tiẹ mọ bi mo ṣe le ṣalaye bi gbogbo ọrọ naa ṣe lọ. Mo waa fẹẹ lo anfaani yii lati bẹ Aunty Funkẹ pe ki wọn dari ji mi, nitori ọmọde ki i mọ ẹkọọ jẹ ko ma ra a lọwọ. Mo bẹ yin kẹ ẹ ma binu ni gbogbo ọna ti mo ba gba fi ṣe nnkan to dun yin, ati atẹjiṣẹ meeli (mail), ti wọn fi ṣọwọ si yin naa, mo mọ pe o dun yin, nitori bẹẹ ni mo ṣe n bẹbẹ.

Ẹ jọọ, ẹ fori aimọkan mọkan ọmọde ti mo hu sẹyin ji mi, Ẹ jọọ ẹ ma binu si mi.

Mo nifẹẹ yin titi lae, Aunty Funkẹ”.

Bakan naa lo ṣalaye pe oun ko wa sori ẹrọ ayelujara nitori kawọn eeyan le kaaanu oun, tabi pe ki wọn le ba oun bẹ Funkẹ, o ni o kan wu oun bẹẹ ni, nitori awọn ti yanju aawọ aarin awọn.

“Mo fẹẹ pe awọn eeyan si akiyesi, pe o kan wu mi lati ṣe gbogbo eyi ti mo n ṣe yii lori afẹfẹ ni. Ki i ṣe nitori kawọn eeyan le ba mi bẹ wọn. Emi funra mi ti lọọ ba Anti Funkẹ, wọn ti fori ji mi, wọn di mọ mi, wọn gbadura fun mi, koda wọn tun se ounjẹ fun mi bi wọn ṣe maa n ṣe e nigba ti gbogbo nnkan ṣi daa latẹyinwa. Raisi aladapọ jọlọọfu, jọlọọfu ẹlẹmi-in meje, ati furaidi raisi pẹlu adiyẹ to dun ni wọn se fun mi.

Ọmọ wọn ni mo jẹ titi lae, eeyan daadaa kan bayii ni wọn. Awọn asiko daadaa to ti lọ yẹn tun ti de pada o, mo si fẹ ki gbogbo yin maa foju sọna. Mo nifẹẹ gbogbo yin. Ẹ ṣe pupọ”.

Bayii ni Juliana, tawọn eeyan mọ si Toyọ bebi, kọ ọ sori ẹrọ ayelujara rẹ. Ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn si ti ki i fun igbesẹ akinkanju to gbe, pẹlu bo ṣe ronupiwada lati bẹbẹ fun aṣiṣe atẹyinwa rẹ, ati bo ṣe pa itiju ti, to gba ori ayelujara lọ lati jẹwọ ẹṣẹ ati lati tun aarin oun ati Funkẹ, to pe ni Anti ẹ ṣe.

Bakan naa ni Funkẹ Akindele paapaa ti fesi ninu ọrọ to gbe si ori Instagraamu rẹ, o ni ọmọ oun ni oṣere naa titi aye, oun si nifeẹ rẹ gidigidi. Latigba ti Funkẹ ti gbe ọrọ yii jade lawọn eeyan ti n ki i, ti wọn si n ṣadura fun un pe o huwa agba, iwuri lo si jẹ fun awọn.

Lara awọn oṣere to ti dupẹ lọwọ Funkẹ tawọn eeyan tun maa n pe ni Jenifer yii ni Toyin Adewale, ẹni to ṣadura fun oṣere yii.

Leave a Reply