Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Adedeji Adeṣọla Tobilọba to jẹ ẹlẹrii keje ninu ẹjọ ti wọn fi kan oludasilẹ ileetura Hilton, niluu Ileefẹ, Dokita Adedoyin, lori iku akẹkọọ Fasiti Ifẹ, Timothy Adegoke, ti sọ funle-ẹjọ pe oun ni oloogbe naa ba lẹnu ọna ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla, ọdun 2021 to wa.
Adeṣọla ṣalaye pe loootọ ni alakooso otẹẹli naa, Roheem Adedoyin, wa si ibẹ ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ naa, nigba ti baba rẹ ṣabẹwo sibẹ ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ, ṣugbọn ko si eyi to wọnu yara 305 ti Timothy sun si.
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, ko ti i si alejo kankan to waa gba otẹẹli ki Timothy too de, nigba to si de, ti manija fi awọn yara ti owo wọn jẹ ẹgbẹrun mejidinlogun aabọ Naira (#18,500) han an, o gba ọkan nibẹ, o si sọ pe ọjọ meji loun fẹẹ lo.
O ni awọn nilo owo lati fi ra epo diisu lọjọ naa loun ati manija, Kazeem Oyetunde, ṣe gba pe ki Adegoke sanwo sinu akanti UBA oun lẹyin to sọ pe tiransifa loun fẹẹ fi sanwo.
Bo si ṣe sanwo tan ni oun fun manija ni kaadi ATM oun, ti iyẹn si lọọ gba owo lati fi ra epo diisu. Lẹyin Timothy, Adeṣọla ṣalaye pe alejo mẹẹẹdogun mi-in lo tun gba yara nibẹ lalẹ ọjọ naa.
Adeṣọla sọ siwaju pe ni nnkan bii aago mejila alẹ ni oun kadii akanti ọjọ naa nilẹ, ti oun si fi foonu oun ya fọto awọn akọsilẹ ti oun ṣe fọjọ naa.
O ni nigba to di aarọ ọjọ keji, iyẹn ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ti Magdalene Cheifuna de lati gbaṣẹ lọwọ oun, oun sọ fun un pe ninu gbogbo awọn alejo ti wọn wa ni otẹẹli, awọn meji pere ni wọn sanwo ọjọ meji.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ẹka ileetura naa, Hilton Hotel Royal, loun wọṣẹ si lọjọ keje, oṣu Kọkanla, ọdun naa.
O ni nitori pe o ti bọ si ipari ọsẹ, aarọ ọjọ Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu Kọkanla, loun too lọọ san owo ti oun pa lọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, si banki Stanbic IBTC, Ileefẹ, nigba ti oun lọọ sanwo to wọle ni ọjọ keje ni banki Wema.
Latari imurasilẹ to n ṣe nipa igbeyawo ẹgbọn rẹ, Adeṣọla ṣalaye pe oun ko lanfaani lati mu tẹla (teller) ileefowopamọ lọ si ileetura naa, oun si fi to Magdalene leti.
O ni nigba to di ọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla, ọkan lara awọn akọwe ileetura naa, Quadri Moshood, pe oun lori foonu pe ayẹwe-owo wo fẹẹ ri oun latari bi akọsilẹ owo to wọle laarin ọjọ karun-un si ọjọ keje, oṣu Kọkanla, ṣe di awati.
O ni oun lọ sọdọ Moshood pẹlu awọn tẹla ọwọ oun, o si dari oun si ọdọ ayẹwe-owo wo to wa ni The Polytechnic, Ifẹ, oun si ṣalaye pe nitori pe awọn ọjọ naa bọ si opin ọsẹ loun ko ṣe raaye ko wọn wa.
Adeṣọla ni ilu Ileṣa loun wa lọjọ kọkanla, oṣu Kọkanla, nigba ti Esther Ashigor pe oun lori foonu pe ipade pajawiri kan wa nile alaga awọn, Dokita Adedoyin, to wa lagbegbe Parakin, niluu Ileefẹ.
O ni oun ti kọkọ sọ fun un pe oun ko ni i le raaye wa, ṣugbọn nigba ti Quadri tun pe oun lori foonu nipa ipade naa, loun pinnu lati lọ laaarọ ọjọ naa.
O fi kun ọrọ rẹ pe nigba ti oun de ile Adedoyin, Roheem mu oun lọ sẹgbẹẹ kan, o si sọ pe awọn ọlọpaa ti n wa alejo kan ti oun gba sinu yara 305, to si san owo sinu akanti oun. Roheem fun oun ni iwe kan lati tun akọsilẹ awọn alejo to wa lotẹẹli lọjọ naa kọ, lai si orukọ Timothy nibẹ.
O ni lẹyin eyi lawọn pada sọdọ Adedoyin, to si sọ pe ṣe loun (Adedoyin) fẹẹ ran oun (Adeṣọla) lọwọ lori ọrọ naa. O ni Adedoyin ni oun ko gbọdọ sọ fun awọn ọlọpaa pe Timothy sun sinu otẹẹli lalẹ ọjọ yẹn, ṣe ni ki oun sọ pe o kan waa beere iye yara, o si gba nọmba akanti oun.
O ni titi ti oun fi kuro ni otẹẹli laaarọ ọjọ naa ni ẹrọ to n ka aworan silẹ (CCTV) n ṣiṣẹ, ṣugbọn nigba ti oun pada sẹnu iṣẹ lọjọ kẹsan-an, oṣu Kọkanla, loun ri i pe wọn ti yọ mọnitọ (monitor).
Lẹyin gbogbo awijare, gbogbo awọn agbẹjọro fẹnu ko lori ọjọ ti onikaluuku yoo fẹsẹ awijare rẹ mulẹ (adoption of written addresses), Onidaajọ Adepele Ojo si mu ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹfa, ọdun yii, fun eleyii.