Faith Adebọla
Ọkan lara awọn oludije fun tikẹẹti ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti fi awọn alatilẹyin ati ololufẹ ẹ lọkan balẹ pe didun lọsan yoo so fun ẹgbẹ APC ati foun lẹnu erongba ẹ ọhun, o ni ẹṣin to ṣiwaju lẹgbẹ awọn, iwaju loun naa si wa, oun ni tikẹẹti naa maa ja mọ lọwọ, lagbara Ọlọrun.
Ọṣinbajo, to tun jẹ Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, sọrọ yii niluu Abuja lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un yii, lasiko to lọÓ yọju si igbimọ to n tọpinpin awọn oludije funpo aarẹ ọhun lati mọ bi wọn ṣe kunju oṣuwọn si, ni olu-ile ẹgbẹ APC, l’Abuja.
Bi Yẹmi ṣe n jade bọ latọdọ awọn igbimọ naa lawọn ololufẹ rẹ atawọn oniroyin ti duro de e lati mọ bi eto naa ṣe lọ si, Ọṣinbajo si fi wọn lọkan balẹ pe golo-ginni ti adiẹ n ti oko emọ bọ ni, o ni igbimọ naa fọwọ si i pe oun wẹ, oun yan kanin-kanin, lati dije.
Wọn tun beere lọwọ ẹ nipa bo ṣe ri eto idije to fẹẹ waye naa si, boya ọkan ẹ balẹ lati ri tikẹẹti ẹgbẹ gba, Ọṣinbajo fesi pe:
“Ọpọ nnkan la sọrọ le lori nigba ti mo wọle, a sọrọ to kan orileede wa lapapọ ati eyi to kan ẹgbẹ oṣelu wa, a bara wa sọrọ daadaa, ijiroro naa si lọ bo ṣe yẹ. Bẹẹ ni o, iwaju awọn ẹgbẹ oṣelu yooku la wa, iwaju gidi ni, APC lo ṣiwaju.
Gbogbo nnkan ṣi n lọ bo ṣe yẹ ko lọ. Mo gbagbọ pe lagbara Ọlọrun, awa la maa bori.”
Yatọ si Ọṣinbajo, awọn oludije ti wọn ti yọju si igbimọ oluṣewadii naa ni Gomina ipilẹ Eko tẹlẹri, Bọla Tinubu, olori awọn aṣofin, Ahmed Lawan, minisita tẹlẹri, Rotimi Amaechi, Ogbonnaya Onu, Godswill Akpabio ati Chukwuemeka Nwajiuba.
Bakan naa lawọn gomina bii Kayọde Fayẹmi ti ipinlẹ Ekiti, Yahaya Bello ti Kogi, Badaru Abubakar ti Jigawa, Ben Ayade lati Cross River ati David Umahi ti ipinlẹ Ebonyi.
Awọn mi-in ni Sẹnetọ Ken Nnamani, Dimeji Bankọle, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, Sẹnetọ Ajayi Boroffice, Sẹnetọ tile ẹjọ ṣẹṣẹ fun ni beeli, Rochas Okoroacha, Pasitọ Tunde Bakare, Uju Ken-Ohanenye, Nicholas Felix, Ahmad Rufai Sani, Tein Jack-Rich, ati Ikeobasi Mokelu.