Aderounmu Kazeem
Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ orilẹ-ede yii, Muhammed Buhari, ko s̀ọrọ nipa agbako to ṣẹlẹ sọpọ awọn ọdọ ti wọn n ṣewọde tako awọn ọlọpaa SARS ni too-geeti Lẹki, sibẹ, igbakeji ẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, ti sọ pe adanu nla ni.
Ọjọgbọn onimọ ofin yii sọ pe bi oun ti ṣe gbadura fun awọn to ba iṣẹlẹ ọhun lọ, bẹẹ gẹgẹ loun ba awọn mọlẹbi wọn kẹdun gidigidi, ki Ọlọrun ma jẹ ki a tun ri iru ẹ mọ lorilẹ-ede wa.
O fi kun ọrọ ẹ pe oun ti ba awọn kan to wa lọsibitu sọrọ, bẹẹ loun kẹdun awọn ọlọpaa atawọn araalu ti ẹmi wọn bọ ninu iṣẹlẹ naa.
O ni, pupọ ninu ohun tawọn eeyan padanu ni wọn le ma ri mọ, ṣugbọn idajọ to yẹ yoo waye lori gbogbo ẹni ti iya jẹ lọna aitọ. Bẹẹ gẹgẹ lo ṣeleri atilẹyin ẹ fun ipinlẹ Eko atawon ipinlẹ mi-in ti ọrọ kan lori iṣẹlẹ yii.