Ọṣinbajo yoo ṣepade pẹlu awọn ṣenetọ APC

Jọkẹ Amọri
Ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ireti wa pe Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, yoo gbalejo awọn sẹnetọ to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC atawọn alẹnulọrọ mi-in, nibi ti yoo ti ṣinu aawẹ pẹlu wọn nile rẹ to wa ni Akinọla Aguda, niluu Abuja.
Olori awọn aṣofin yii, Ahmad Lawan, lo ka iwe ipe naa seti awọn aṣofin ẹlẹgbẹ rẹ nileegbimọ wọn.
Ireti wa pe Ọṣinbajo yoo lo anfaani iṣinu pẹlu wọn yii lati fi erongba rẹ han pe oun fẹẹ dupo aarẹ Naijiria.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lo ṣinu pẹlu awọn gomina APC, naa nibi to ti fi ipinnu rẹ lati dupo aarẹ han.
Ọjọ keji, eyi ti i ṣe ọjọ Aje, lo si kede fun gbogbo ọmọ Naijiria pe oun fẹẹ dupo aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Leave a Reply