Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ni bayii ti gbedeke gbigba fọọmu fun ẹnikẹni to ba fẹẹ dupo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ti wa sopin lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, eeyan mẹfa lo ti fi erongba wọn han lati dupo naa nipa gbigba fọọmu idije.
Sẹkiteeriati ẹgbẹ naa ni olu ilu ilẹ wa, l’Abuja, ni wọn ti lọọ gba fọọmu naa pẹlu miliọnu mọkanlelogun naira, ti apapọ owo awọn mẹfẹẹfa si jẹ miliọnu mẹrindinlaaadoje naira (#126m).
Awọn mẹfa ti wọn gba fọọmu naa ni Sẹnetọ Ademọla Adeleke, Alhaji Fatai Akinade Akinbade, Dokita Akin Ogunbiyi, Ọnarebu Sanya Omirin, Ọmọọba Dọtun Babayẹmi ati Ọgbẹni Dele Adeleke.
Lati Ẹdẹ ni Sẹnetọ Demọla Adeleke ati Ọgbẹni Dele Adeleke ti wa, Ọgbaagba ni Alhaji Fatai Akinbade ti wa, nigba ti Dokita Akin Ogunbiyi jẹ ọmọ ilu Ile-Ogbo.
Ni ti Ọnarebu Sanya Omirin, ọmọ bibi ilu Ileṣa ni, nigba ti Ọmọọba Dọtun Babayẹmi wa lati ilu Gbọngan.
Ni bayii ti iye awọn oludije wọn ti foju han, irinajo si ibo abẹle lati mu ẹni kan ṣoṣo ti yoo koju awọn oludije latinu ẹgbẹ oṣelu yooku ninu ibo oṣu keje, ọdun 2022 lo ku ti awọn eeyan n duro de.