Dada Ajikanje
Ni bayii, ija ‘emi ni mo ni in’, ‘iwọ kọ lo ni in’ to ti n waye laarin ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun lori ọrọ Yunifasiti Imọ Ẹrọ, iyẹn Ladoke Akintọla University of Technology, LAUTECH, to wa niluu Ogbomọsọ, nipinlẹ Ọyọ, ti rodo lọọ mumi pẹlu bi ajọ to n mojuto ọrọ ileewe giga fasiti nilẹ yii, (National Universities Commission, NUC), ṣe faṣẹ si i pe ki fasiti naa di ti ipinlẹ Ọyọ patapata. Ipinlẹ Ọṣun naa ti gba pe ki eleyii ri bẹẹ.
ALAROYE gbọ pe igbesẹ naa ṣee ṣe pẹlu idasi ajọ to n mojuto ọrọ ileewe giga yunifasiti nilẹ wa, (NUC). Awọn alaṣẹ ibẹ ni wọn da si i, ti wọn si rọ ipinlẹ mejeeji lati wo o ṣe fun ara wọn, ki ohun gbogbo le maa lọ bo ṣe yẹ.
Awọn gomina ipinlẹ mejeeji ni wọn jọ jokoo, ti wọn jọ fikun lukun, ti wọn si kowọ bọwe adehun lori igbesẹ yii, beẹ ni awọn kọmiṣanna feto idajọ ipinlẹ mejeeji lo wa nibẹ gẹgẹ bii ẹlẹrii.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ti fọwọ si i pe ki yunifasiti naa di ti ipinlẹ Ọyọ nikan, sibẹ, ajọsọ wa pe ki ileewe ti wọn ti n kọ nipa eto ilera to jẹ ti yunifasiti naa, iyẹn, College of Health Sciences to wa niluu Oṣogbo jẹ ti ipinlẹ Ọṣun.
Ọdun 1990 ni wọn da ileewe naa silẹ to si jẹ ajọni pẹlu ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun. Ṣugbọn latigba naa ni nnkan ko ti fara rọ, ti awọn ipinlẹ mejeeji yii ko si le da mojuto ileewe ọhun pẹlu bi wọn ṣe jẹ awọn olukọ lowo oṣu repẹte, eyi to ṣe akoba gidi fawọn akẹkọọ nitori bi awọn olukọ wọnyi ṣe n dasẹ silẹ nitori airowo oṣu gba.
Ijọba Adebayo Alao Akala lo kọkọ gbe igbesẹ lati sọ ileewe naa di ti ipinle Ọyọ nikan, ṣugbọn ko ṣee ṣe fun un nitori ọrọ oṣelu to wọ ọ nigba naa.
Ija kekere kọ ni awọn akẹkọọ ileewe naa ba gomina ipinlẹ Ọyọ telẹ, Oloogbe Abiọla Ajimọbi, ja lasiko idaṣẹsilẹ awọn olukọ ileewe naa.
Ọpọ akẹkọọ lo fi ileewe yii silẹ pẹlu bi wọn ṣe n fi gbogbo igba ti i pa, to si n di eto ẹkọ lọwọ.
Ṣugbọn ni bayii to ti di ti ipinle Ọyọ nikan, ireti wa pe amojuto to peye yoo le wa fun un, awọn akẹkọọ yoo si le kawe wọn lai si ifakoko ṣofo kankan mọ.